Homosexual: Uganda yóò dá ẹ̀wọǹ gbére fún obinrin tabi okunrin tó bá fẹ́ ara wọn

Orile ede Uganda Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awon omo ile Uganga ko gbodo fẹ akọ si akọ ati abo si abo

Ijọba ilẹ Uganda ti bẹrẹ igbesẹ lati gbogun ti iwa pe ki ọkunrin meji tabi obinrin meji maa fẹ arawọn.

Ẹni ti o jẹ Minisita fun eto iwa amuyẹ ni ilẹ naa,lo sọrọ igbesẹ ti wa lati mu amuto ba ofin naa ti ile ẹjọ gbegi le ni ọdun 2014.

Simon Lokodo sọ fun awọn eniyan pe ti gbogbo eto ba ti to tan, ẹwọn gbere ni fun ẹnikẹni ti ade ọrọ naa ba ṣi mọ lori.

Lokodo ni wọn yoo jẹ ko ye gbogbo eniyan pe ẹnikẹni tabi eeyan keeyan to ba tasẹ agẹrẹ si ofin yii, yoo dara rẹ lẹbi ti yoo si gba idalẹbi.

Ko ṣai mẹnu baa wi pe, o jẹ ohun ajeji pata gbaa si ilẹ Uganda ki okunrin meji tabi obinrin meji maa ni ajọsepọ.

Ni ọdun 2014 ni Aarẹ Yoweri Museveni ti fọwọ si abadofin naa ṣugbọn ti ile ẹjọ ko gbaa wọle fun idi kan tabi omiran pe ki wọn pa ẹni ba dan iru rẹ wo.

Lokodo ti wa ṣalaye pe ofin tuntun naa ti gba ifọwọ si Aarẹ ati ọga Ọlọpaa pe wọn ti ṣetan lati fi iya jẹ iru ẹni bẹẹ ati ohunkohun to ba ṣẹlẹ lẹyin rẹ.

Pepe Julian Onziema ti o wa lati ẹya to kere ju ni ilẹ Uganda ti ṣalaye pe ẹru paapaa n ba awọn ọmọ ẹgbẹ oun ti ọpọ ẹniyan si ti salọ kuro ni ilẹ naa gẹgẹ bi atipo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKemi Lala: mo ń gbìyànjú láti mú inú òbí mi dùn

Onziema ṣalaye pe ni ọdun yii nikan, wọn ti pa ọkunrin mẹta ati obinrin kan ti wọn lọwọ ninu iru iwa yii, pe ni ọsẹ to kọja ni wọn pa ọmọkunrin kan ti o jẹbi iru ẹsun bẹẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionInú mi dùn pé ọmọ obinrin nìkan ni mo bi

Awọn Orilẹ ede ti o tako iru iwa bẹẹ ti wọn si gba pe iku ni ere ẹṣẹ ẹni bẹẹ ni;

  • Somalia
  • Sudan
  • Saudi Arabia
  • Pakistan
  • Afghanistan
  • Iran
  • Iraq
  • Mauritania
  • Qatar
  • Yemen

Bakan naa ni apa ila Oorun orilẹ ede Nigeria, okuta ni wọn maa n ju pa iru ẹni ti ade ọrọ naa ba ṣi mọ lori.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCS Mum: Omotolani Ekene ní ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ọ̀lẹ, arugún, aláìlera ni ẹni tó fi abẹ bímọ