Kaduna kidnap: Akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà mórí bọ́ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé

Awọn ohun ija ogun Image copyright Nigerian Army
Àkọlé àwòrán Kaduna kidnap: Akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà mórí bọ́ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé

Ọpẹ o! Awọn akẹkọọ mẹfa ti wọn jigbe ni ileewe girama ni Gwagwada, nipinlẹ Kaduna ti gba ominira bayii.

Ileeṣẹ ologun orilẹ-ede Naijiria lo fọrọ naa lede ninu atẹjade kan ti wọn fi sita.

Ileesẹ ologun ṣalaye pe ọwọ ti tẹ awọn ajinigbe ọhun, ati pe awọn tun ti gba oriṣiiriṣii ohun ija lọwọ wọn.

Ileeṣẹ ologun ni awọn akẹkọọ naa n lọ si ileewe nigba ti awọn ajinigbe ọun gbe wọn lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKemi Lala: mo ń gbìyànjú láti mú inú òbí mi dùn

Lẹyin ija ajaku akata laarin awọn ologun atawọn ajinigbe ọun nibi ti ọkan ninu awọn ajinigbe naa ti farapa.

Àkọlé àwòrán Ohun oju ri to!

Eleyi ni igba kẹta ti iṣẹlẹ ijinigbe yoo waye nile iwe laarin ọsẹ meji nOlúwaṣeuni Kaduna.

Koda iṣẹlẹ ijinigbe kan tun ṣẹlẹ l'Ọjọbọ nibi ti wọn ti ji ọga ileewe kan lọ.

Ileeṣẹ ologun sọ pe awọn akẹkọọ fẹsẹ fẹ ni kete tawọn ajinigbe de ileewe wọn ti wọn si ji ọga ileewe naa lọ.

Opọ eyan Naijiria lo ti gboriyin fawọn ọmọ ogun to doola awọn akẹkọọ naa pe iṣẹ takuntakun ni wọn ṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSuicide Prevention: ìwọ́de yìí wáyé láti gbógun ti pípa ara ẹni

A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin laipẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCS Mum: Omotolani Ekene ní ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ọ̀lẹ, arugún, aláìlera ni ẹni tó fi abẹ bímọ
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKini Yoru[bá ń pe Necklace?