2020 Budget Defence: Buhari láwọn mínísítà kò gbọdọ̀ rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèrè

Muhammadu Buhari pẹlu awọn oṣiṣẹ ijọba apap\u Image copyright Twitter/Bashir Ahamd

Aarẹ Muhammadu Buhari f'ofin de awọn minisita atawọn oṣiṣẹ ijọba miiran ti wọn n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ aarẹ lati rinrin ajo lọ si oke okun.

Ọfiisi akọwe ijọba apapọ lo fi ọrọ yii lede lọjọ Ẹti, bakan naa lọrọ naa wa loju opo Twitter ileeṣẹ Aarẹ.

Igbesẹ yii nijọba gbe lati fun awọn minisita lanfaani lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ile aṣofin agba lori eto isuna ọdun 2020 fun orilẹede Naijiria.

Eyi tumọ si pe awọn minisita yoo lanfaani lati maa rinrinajo pada silẹ okere lẹyin ti Aarẹ Buhari ba ti gbe eto iṣuna lọ siwaju ile aṣofin tan, ti wọn si gba a wọle.

Ọjọ Iṣẹgun ni Aaarẹ gbe aba iṣuna to le ni tiriliọnu mẹwaa lọ siwaju ile aṣofin agba l'Abuja.

Aarẹ Buhari ti sọ tẹlẹ pe oun fẹ ki orilẹede Naijiria bẹrẹ si lo eto isuna ti yoo bẹrẹ ni oṣu kinni, ti yoo si pari ni oṣu kejila.

Ẹwẹ, adari ile aṣofin agba l'Abuja, Ahmed Lawan sọ pe awọn aṣofin yoo gbiyanju agbara wọn lati ri i pe awọn ṣiṣẹ pọ pẹlu Aarẹ Buhari lori aba eto isuna to gbe wa siwaju ile.

Lawan ṣalaye pe ile ti ya oṣu kẹwaa yii sọtọ fun ẹlẹkajẹka ileeṣẹ ijọba lati wa sọ nipa eto isuna wọn ki o le ya kiakia.