2020 Budget: 'Owó oṣù sísan ni ọ̀pọ̀ àbá ètò ìṣúná fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá àtàwọn ológun yóò bá lọ'

Tukur Buratai ati Muhammed Adamu Image copyright Nigerian Army

Ohun ti wọn lee se ni ki wọn maa san owo ohun ti wọn ba ra diẹdiẹ -Onwoye

Njẹ eto aabo to mẹhẹ lorilẹ-ede Naijiria le lojutu ni ko pẹ ko jina?

Ibeere ti ọpọ ọmọ Naijiria n beere ni yii lẹyin ti aba eto iṣuna ọdun 2020 fihan pe ida aadọrun un le kan ni ileeṣẹ ọlọpaa atawọn ologun yoo na lori owo oṣu.

Aba eto iṣuna naa fihan pe owo ajẹmọnu ati owo oṣu awọn agbofinro atawọn ọmọ ogun lo fẹẹ gba gbogbo owo tan ninu eto iṣuna ọhunWo gbèsè tí Nàìjíríà ti jẹ láàrin ọdún 2015 sí 2019 .

Ati pe ida mẹsan an pere ninu ọgọrun un si wa fun rira ohun eelo ijagun ati awọn iṣẹ akanṣe.

Awọn onwonye sọ pe eleyi ko ni fawọn ileeṣẹ ọlọpaa ati ologun lanfaani lati ra awọn nnkan ija ogun, ohun ti wọn lee se ni ki wọn maa san owo ohun ti wọn ba ra diẹdiẹ Ilé ìgbìmọ aṣofin ti dájọ tí wọn ó fọwọsi àbádofin ìsúna 2019.

Ọjọ Iṣẹgun ni Aarẹ Muhammadu Buhari gbe aba eto iṣuna fun ọdun 2020 to le ni tiriliọnu mẹwaa lọ siwaju ile aṣofin agba l'Abuja.

Tiriliọnu to din diẹ ni marun un ni yoo ba owo sisan lọ ninu eto iṣuna na, nigba ti tiriliọnu meji pere wa fun iṣẹ akanṣeBuhari ti fòfin de àwọn mínísítà láti rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèrè.

Awọn onimọ ninu ọrọ eto aabo ni o ṣeeṣe ki iyatọ maa ba eto aabo to mẹhẹ lọdun 2020 nitori owo ti ijọba ya sọtọ fun ileeṣẹ ọlọpaa atawọn ologun ti kere ju.

Ọgbẹni Rekpene Bassey to jẹ onimọ lori eto aabo sọ pe owo kereje lowo ti ijọba ya sọtọ fun eto ti wọn ba parọ rẹ lati naira si owo dọlaÒpópónà àti afárá 19 níjọba fẹ́ ṣe nínú àbá ìṣúná ọdún 2020.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKemi Lala: mo ń gbìyànjú láti mú inú òbí mi dùn

Bassey ni eto aabo yoo mẹhẹ si lọdun 2020 nitori owo to wa ninu aba eto iṣuna fọdun to n bọ ti kere ju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDavid Adiatu oníṣẹ́ ọnà pẹ̀lú ìṣó àti òwú