Child sexual abuse: Ìdí rèé tí mi ò fi sọ̀rọ̀ nígbà tí ìbátan mi fipá bá mi lopọ̀ l'ọdún 67 sẹ́yìn

Aworan ọmọ ti wọn ipa ba lopọ
Àkọlé àwòrán Child sexual abuse: Ìdí rèé tí mi ò fi sọ̀rọ̀ nígbà tí ìbátan mi fipá bá mi lopọ̀ l'ọdún 67 sẹ́yìn

Ifipabanilopọ lo yẹ ki tonile-talejo fọwọsowọpọ gbogun ti.

Ilumọọka oniroyin lorilẹ-ede Ghana, to tun jẹ minisita tẹlẹ ri, Elizabeth Ohene lo sọ iriri rẹ lori bi wọn ṣe fipa ba a lopọ ni bi ọdun mẹtadinlaadọrin sẹyin.

Ọmọ ọdun meje ni Ohene wa nigba ti iṣẹlẹ naa waye, ṣugbọn ko sọ fun ẹnikan nigba naa.

Nigba to n ṣalaye idi abajọ ti ko fi sọ iru iṣẹlẹ nla fun ẹnikẹni, Ohene ni oun o mọ ohun tawọn eeyan yoo sọ t'oun ba gbe igbesẹ lati sọ ohun to ṣẹlẹ si oun sita.

Ohene ti le ọdun mẹrinlelaadọrin ọdun bayii, ko to ṣẹṣẹ gbe igbesẹ lati sọ ohun to ṣẹlẹ sii ni ọgọta ọdun o le diẹ sẹyin.

O ni awọn iroyin ti oun n ka nipa iwa ifipabanilopọ ko dun un gbọ leti, eyi lo jẹ ki oun ṣiṣọ loju eegun iriri t'oun naa to jẹ iso inu ẹku tẹlẹ.

Ṣugbọn ibeere ti oun gbọdọ wa idahun si ni pe kilode ti oun fi sọrọ yii lasiko yii ti oun ti sun mọ ọgọrin ọdun laye?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionInú mi dùn pé ọmọ obinrin nìkan ni mo bi

Iriri mi ree:

Mo gbe igbesẹ lati sọ iriri ifipabanilopọ ti mo ni lati rii wi pe iru iṣẹlẹ bẹẹ ko ṣẹlẹ sawọn ọmọbinrin keekeeke bii temi nigba ti mo wa ni ọmọ ọdun mẹtala.

Ọrọ tawọn eeyan yoo sọ lawujọ ko gbami laaye lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ si mi ni pato.

Ohun ti mo kan sọ ni pe mo ni iriri ifipabanilopọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ohun ti mo kan sọ ni pe mo ni iriri ifipabanilopọ.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ si Elizabeth?

Ni ọdun 1952, mo wa ni ọmọ ọdun meje nigba ti mo n gbe pẹlu mama to bi mama mi ni abule wa.

Ṣugbọn lọjọ kan, ọkunrin kan to jẹ ibatan mi kan to n gbe lẹgbẹ ile wa ṣaadeede fa mi lọ si inu ile rẹ nibi to ti fipa bami lopọ.

''N ko tilẹ mọ ohun ọkunrin yii ṣe fun mi nigba naa, ṣugbọn ohun ti mo le ranti ni pe o fi ọwọ rẹ to dọti bọ oju ara mi.''

Àkọlé àwòrán ṣugbọn ohun ti mo le ranti ni pe o fi ọwọ rẹ to dọti bọ oju ara mi.''

Ohene sọ pe oun ko le gbagbe oorun ara ọkunrin naa ati eekanna rẹ to fi bọ oju ara ohun titi di ọjọ oni ti iṣẹlẹ naa ti pe ọdun mẹtadinlaadọrin.

''Ṣugbọn lonii, o ti yemi ni pato ohun ti ọkunrin yii ṣe fun mi ni ọdun mẹtadinlaadọrin sẹyin.''

Mama mama mi ni o n ṣe itọju mi nigba naa, bo tilẹ jẹ pe mo kọ lati sọ ohun to ṣẹlẹ fun un.

''Mama mama mi kan ṣaadeede ṣakiyesi pe etutu n jade lati oju ara mi nigba ti wọn n wẹ mi, ṣugbọn wọn ko tiẹ lero wi pe bo ya ibatan wa lo ṣe okunfa rẹ.''

''Mama mama mi ko tilẹ beere ohun kan lọwọ mi, o kan ṣaa tọju mi ni.''

Àkọlé àwòrán 'Mama mama mi ko tilẹ beere ohun kan lọwọ mi, o kan ṣaa tọju mi ni.''

Ṣugbọn nigba ti mo pe ọmọ ọdun mọkanla, ọkunrin kan naa tun fipa bami lopọ!

''Mi ko si le sọ bakan naa lẹyin iṣẹlẹ keji yii pe oye iru ipa tawọn iṣẹlẹ yii yoo ni lori mi.

Ṣugbọn ohun ti mo le sọ bayii ni pe mo la awọn iṣoro yii kọja, bo tilẹ jẹ pe wọn ṣakoba fun mi ninu ero mi.''

Elizabeth ni: ''Mo gbe igbesẹ lati sọrọ yii lasiko yii nitori mo ti gbe ile aye ṣerere, gẹgẹ bi oniroyin ati minisita tẹlẹri lorilẹ-ede Ghana.

Ti mo ba ku bayii, awọn eeyan yoo ri nnkan rere tọka si nipa mi.''

''Ohun miiran to mu mi sọ iriri mi ni pe ọpọ lo ri ifipa ba awọn ọmọdebinrin lo pọ si ohun ti ko too pọn ọn.

Ọpọ awọn agbalagba ọkunrin lo n fipa bawọn ọmọde lopọ lasiko yii, tawọn eeyan ko si sọ ohun kan nipa rẹ.''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption"Sex for grades": Undercover in West African universities

''Ti awọn ẹbi ọmọde ti wọn ba lajọṣepọ bakẹjọ lọ sọdọ awọn ọlọpaa, ẹjọ naa ko ni lojutu nitori awọn ọlọpaa naa ni yoo gbawọn nimọran lati lọ yanju ọrọ naa ni itubi inunbi laarin ara wọn nile.''

''Ohun ti mo fi sọrọ ni pe awọn ọmọ ọdun mẹta ati ọdun meje miiran tun le ni iru iriri buruku ti mo ni yii lọpọ ọdun sẹyin.''

Ifẹhonuhan lori awọn akọ to n ṣe ṣakọ ati abo sabo:

Ohene lo ṣe ni laanu pe ọpọ lo sọrọ tako awọn akọ to n fẹ akọ ara wọn nigba ti wọn fi awọn to n fipa bawọn ọmọde silẹ.

'Iṣẹlẹ ifipa bọmọde lopọ yoo tẹsiwaju niwọn igba ti awọn eeyan ko tii ṣetan lati maa sọ nipa rẹ.''

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán 'Iṣẹlẹ ifipa bọmọde lopọ yoo tẹsiwaju niwọn igba ti awọn eeyan ko tii ṣetan lati maa sọ nipa rẹ.''

Inu mi yoo dun ti iriri mi ba ti ṣeranwọ fun ẹnikan:

Ọpọ lo ti n sọ ero wọn lati igba ti mo ti fi iriri mi sita eleyi to jẹ iwuri fun mi. Ko da ọpọ wọn lo sọ pe ko ṣee gbọ seti.

''Ko jẹ iyalẹnu fun mi pe awọn eeyan n sọ pe ohun to ṣẹlẹ si mi ko ṣee maa sọ.

Awọn kan tiẹ sọ pe ko yẹ ki n maa sọ iru iṣẹlẹ buruku yii fawọn eeyan lawujọ, ṣugbọn n ko ni ọrọ lati ba iru awọn bẹẹ sọ.''

''Bakan naa lọpọ obinrin ti sọ fun mi pe iriri mi ti fun awọn naa ni igboya lati bori iru iṣoro bayii tawọn naa n doju kọ; Eyi jẹ idunnu fun mi.''

''Maa fọwọ rọri ku, ti iriri mi yii ba le jẹ ki ọpọ bẹrẹ si sọrọ lori iwa ifipabanilopọ ati ọna abayọ si iṣoro yii.''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCOZA: Ọpọ èrò ló jáde ṣe lòdì sí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ Fatoyinbo