Yollywood: Odunlade fijó bẹ́ẹ, Lizzy padà sọ́dún 2012, Lateef gbàmì ẹ̀yẹ tuntun

Toyin Abrahama, Odunlade Adekola ati Lizzy Anjonrin Image copyright Instagram
Àkọlé àwòrán Yollywood Artists: Odunlade fijó bẹ́ẹ, Lizzy padà sọ́dún 2012, Lateef gbàmì ẹ̀yẹ tuntun

Wọnyi ni diẹ lara awọn nnkan tawọn oṣere Yollywood ṣe lọsẹ yii ti wọn si gbe sori ayelujara nipa ara wọn.

Lizzy Anjọrin:

Ẹ jẹ ki a bẹrẹ pẹlu oṣere yii, Lizzy Anjọrin, lo fi ibeere lede lori oju opo Instagram rẹ pe kawọn ololufẹ oun sọ iru ọkọ ti oun n lo laarin ọdun 2012 si 2013.

Koda, o tun sọ wi pe ẹnikẹni to ba le sọ iru ọkọ ti oun n lo lọdun 2011; oun ṣetan lati fun iru ẹni bẹẹ lẹbun ẹgbẹrun un marun un owo naira.

Lizzy ṣalaye loju opo instagram rẹ pe ayelujara ti mu ayipada ba igbe aye eleyi to si n mu ọpọ eeyan parọ tawọn mii si n wuwa buruku kiri.

Toyin Abraham:

Toyin Abraham ni tirẹ ṣo pe oun lọ tọ nigba mẹwaa laarin iṣẹju mẹẹdogun lati ori itage nigba ti oun n kopa ninu ere #Elevatorbaby pẹlu oyun ninu oun.

Toyin fikun ọrọ rẹ pe igba marun un ni oun lọ mu omi bakan naa laarin iṣẹju mẹẹdogun lori itage.

O ni oyun inu oun ti pe oṣu mẹfa nigba ti oun kopa ninu ere yii.

Afi ki gbogbo abiyamọ jere ọmọw ọn, oyun nini ko rọrun!

'Ìdí rèé tí mo fi ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fipá bámi lopọ̀ lọ́mọ ọdún méje lọ́gọ́ta ọdún sẹ́yìn'

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn òfegè ni pé Buhari fẹ fẹ́ Sadiya, síbẹ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ń ṣètò ìyàwò náà lórí ayélujára

'Títẹ àwọn afipábánilopọ̀ lọ́dàá kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ sí ìwà ìfipábánilopọ̀'

Ọpẹ́ o! Àwọn ologun dóòlà akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà lọ́wọ́ àwọn ajínigbé ní Kaduna

Funke Akindele:

Funke Akindele fi fiimu to ṣẹṣẹ dari sita lori oju opo Instagram rẹ, eyi ti o pe akọle rẹ ni #Your Excellency.

O sọ nipa asiko ti ere naa yoo di wiwo ni kaakiri

Dino Melaye fìdí rẹmi, Smart borí nílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

Ta ni Sadiya Umar Farouq tí ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ń gbé pé òun ló fẹ́ dí ìyàwó tuntun Buhari?

Olùkọ́ àgbà tó fipá bá ọmọ ọdún 13 lò yóò fojú ba ilé ẹjọ́ ni Benue

Uganda ti bẹrẹ ìgbésè láti fi ikú ṣefàjẹ fún ẹní bá ṣe ìgbéyàwó akọ si akọ ati abo si abo

Lẹyin to gboryin fun Baba Ibeji olowo ori Funkẹ pe o ku atilẹyin oun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionInú mi dùn pé ọmọ obinrin nìkan ni mo bi

Laide Bakare:

Ọjọ Aje, ọjọ keje, oṣu kẹwaa ni ọjọ ibi Laide Bakare, eyi to ṣe ni ilu Atlanta, nipinlẹ Georgia l'Amerika.

Oriṣiiriṣii fidio ni Laide fi soju opo Instagram rẹ eleyi to ṣayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.

Odunlada Adekola:

Ijo ni Odunlade Adekola fi bẹ ni tiẹ ninu fidio kan to fi soju opo Instagram rẹ.

Fidio yii lo ṣafihan bi Odunlade ṣe ko mọlẹ pẹlu Mike Edwards to wa lara awọn marun un to pegede julọ ninu eto BBNaija 2019 to ṣẹṣẹ pari

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDavid Adiatu oníṣẹ́ ọnà pẹ̀lú ìṣó àti òwú

Femi Adebayo Salami:

Femi Adebayo Salami to jẹ ọmọ Ọga Bello fi aworan kan sori oju opo ayelujara rẹ eleyi to fi ṣalaye pe ohun kan to rọ oun lọrun ju lati maa ṣe naa ni ere ori itage.

Koda o ni oun le ṣee lọfẹẹ, bakan naa lo bi awọn ololufẹ rẹ lati sọ ohun ti wọn fẹran ju ni ti wọn lati maa ṣe.

Àbà ètò ìṣúná 2020 tó kéré yóò mú kí ètò ààbò mẹ́hẹ síi ní Nàìjíríà-Onwoye

Èrò yapa ní mọ́ṣáláṣí Jimọ̀h láti wá fójú lóúnjẹ lórí ìgbéyàwó òfegè Buhari.

Ìbéèrè àti ìdáhùn pẹ̀lú Seyi Awolowo ti BBNaija lórí BBC Yorùbá

Buhari ti fòfin de àwọn mínísítà láti rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèrè

Lateef Adedimeji:

Lọsẹ yii bakan naa ni oṣerekunrin ni, Lateef Adedimeji gba ami ẹyẹ Emperor Award Stylish Actor.

O ki gbogbo awọn eeyan to dibo fun un loju opo instagram rẹ, bẹẹ naa lo fi ami ẹyẹ ọhun sọri wọn.

Ìdẹ̀ra dé l'Eko! ọkọ̀ ojú omi tuntun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́

Abiy Ahmed gba àmì ẹ̀yẹ̀ ti àláfíà lágbàáyé gẹ́gẹ́ bí ọmọ Africa

Ìgbẹ̀yìn ọkùnrin tó pa obìnrin 93 ni America

Òjò àrọ̀rọ̀ọ̀dá òní ṣọṣẹ́ tó pọ̀ ni Lekki nipinlẹ Eko

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkitiRapeCastration: ìgbésẹ̀ míì lè dẹ́kun ìwà ìfipábánilòpọ̀