BUSA 2019: Èrò yapa ní mọ́ṣáláṣí Jimọ̀h láti wá fójú lóúnjẹ lórí ìgbéyàwó Buhari

Kini o ṣẹlẹ ni Mọṣalaṣi Jimoh lanàá ti wọn royin ofege pe Buhari fẹ ṣe igbeyawo nibẹ?

Lati bi ọjọ mẹta kan ni iroyin ti gbori ayelujara kan pe Aarẹ Muhammadu Buhari fẹ gbe iyawo miran.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Buhari kirun Jimoh laiṣe igbeyawo gẹgẹ bi awọn kan ṣe n sọ kiri

Iroyin naa ni Hajiya Sadiya Umar Farouq ni aarẹ fẹ gbe ni ọsingin ni eyi ti awọn eniyan si fẹ mọ sii nipa rẹ pe Ta ni Sadiya Umar Farouq tí ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ń gbé pé òun ló fẹ́ dí ìyàwó tuntun Buhari?

Hajiya Sadiya ti ẹnu n kun yii wa ninu awọn obinrin meje ti wọn jẹ minista tuntun ti Buhari yanWo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àwọn obìnrin méje ti Buhari fẹ́ yàn sípò minista

Lori ayelujara ni awọn eniyan Naijiria ti ṣeto igbeyawo fun wọn lana Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn òfegè ni pé Buhari fẹ fẹ́ Sadiya, síbẹ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ń ṣètò ìyàwò náà lórí ayélujára

Iroyin to n jade lati ile iṣẹ iroyin Naijiria ni pe ọpolọpọ ero lo wa kirun Jimọ lana ni mọṣalaṣi ile ijọba apapọ ni Aso Rock nilu Abuja to jẹ olu ilu Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAPC: òfin NYSC ti APC fi mú mi ni wọ́n kò lò fi mú Ajimọbi tí a kò jọ sìnrú ìlú

Lara awọn eekan to wa kirun pẹlu aarẹ Buhari lana ni Abdulaziz Yari to jẹ gomina ipinlẹ Zamfara tẹlẹ atawon minista mii.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán ọpọ ero lo fẹ mọ ohun ti a ṣẹlẹ lasiko Jimọh

Koda, iroyin ni ero pọ pupọ ni mọṣalaṣi naa de ibi pe wọn gba pe awọn fẹ wa woran pe boya lootọ nigbeyawo yoo waye laarin Aarẹ ati minista fawọn aṣatipo rẹ tuntun.

Awọn ti wọn tori igbeyawo Buhari ya mọṣalaṣi Aso Rock ni inu wọn ko dun to pe igbeyawo naa ko waye bi ayelujara ṣe kede rẹ.

Ileeṣẹ iroyin Naijiria ni ọpọ ninu awọn to ya wa kirun Jimọ nibẹ naa lo n ṣepe fawọn to bẹrẹ iroyin ofege naa lori ayelujara.

Bakan naa ni awọn bii Aliyu ti wọn wa kirun naa gba awọn ọmọ Naijiria nimọran lati ma gba gbogbo nkan ti wọn ba ka lori ayelujara gbọ nitori irọ pọ nibẹ.

Ni afikun ni awọn bii Malam Sidique to wa kirun ni Aso Rock naa ke si ijọba lati wa wọrọko fi ṣada lori iroyin ẹlẹjẹ to n gab ori ayelujara kan lasiko yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionInú mi dùn pé ọmọ obinrin nìkan ni mo bi

Ṣaaju awọn oluranlọwọ fun Aisha Buhari nileeṣẹ Aarẹ ti sọ fun BBC tẹlẹ pe irọ to jina si ootọ ni iroyin naa.

Bẹẹ minista ti wọn ni Buhari fẹ fẹ wa ni Geneva nilẹ okeere lasiko yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDavid Adiatu oníṣẹ́ ọnà pẹ̀lú ìṣó àti òwú

Lẹyin eyi ni iroyin ni Femi Adesina to jẹ olubadamọran fun Aarẹ Buhari lori eto ifitonileti ti sọ ni Tribune Online pe awọn kan ni wọn gbe irọ naa kalẹ.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo gba pe adura lo ku ki a maa gba fun awọn adari Naijiria lai gba iroyin ofege laaye lati daamu ọkan ẹnikẹni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKemi Lala: mo ń gbìyànjú láti mú inú òbí mi dùn