Oríbíbẹ́ kọ ni oògùn orí fífọ́- Omowe Dare Adelusi
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

EkitiRapeCastration: ìgbésẹ̀ míì lè dẹ́kun ìwà ìfipábánilòpọ̀

Titẹ lọdaa ko sọpe ẹni naa ko ṣi ni le ba obinrin sun -Onimọ.

Ọpọlọpọ nkan ni awọn eniyan ti n sọ nipa abadofin ti ijọba ipinlẹ Ekiti n jiroro lori lasiko yii.

Wọn fẹ maa tẹ awọn to ba ṣe ifipabanilopọ lọdaa 'Títẹ àwọn afipábánilopọ̀ lọ́dàá kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ sí ìwà ìfipábánilopọ̀'

Dokita Dare Adelusi ti oun funra rẹ jẹ ọmọ Ekiti ni ọgbọn miran bii ka gboriyin fun ẹni to ba huwa ọmọluwabi yoo yi ero ọkan oniṣẹ ibi miran pada.

Bakan naa ni ọmọwe yii gbagbọ pe o yẹ ki ijiya to tọ wa fun gbogbo awọn to ba n huwa ipa lawujọ ni eyi ti yoo kọ awọn to ku lọgbọn ni kete ti agba kan ba ti jin si koto.

Dare Adelusi gbe ori yin fun ijọba Ekiti pe wọn fẹ dẹkun iwa buruku yii ṣugbọn o gba pe awọn ọna miran wa nitori titẹ lọdaa le ma gbọ iṣoro yii tan.