LASEMA: Òjò nìkan kọ́, ọkọ̀ aképo méjì tó dànù náà ṣòkùnfà súnkẹrẹ-fàkẹrẹ l'Eko

Aworan ọkọ akepo to danu l'Eko Image copyright lasema
Àkọlé àwòrán LASEMA: Òjò nìkan kọ́, ọkọ̀ aképo méjì tó dànù náà ṣòkùnfà súnkẹrẹ-fàkẹrẹ l'Eko

Ọkọ akepo kan to danu lagbegbe afara Otedola nilu Eko ti mu idiwọ ba lilọ bibọ awọn ọlọkọ lopopona marosẹ Lagos- Ibadan lọjọ Abamẹta.

Eyi ni ọkọ akepo keji ti yoo danu laarin wakati mẹrinlelogun si ara wọn.

Ọga agba ileeṣẹ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri nilu Eko, LASEMA, Ọmọwe Femi Osanyintolu lo tu kẹkẹ ọrọ yi fun ileeṣẹ BBC.

Osanyintolu ni lowurọ ọjọ Abamẹta ni ọkọ to ko epo bẹntiroo oni lita egbẹrun marundinlaadọta, (45, 000) naa danu ti awọn si ti n gbiyanju lati da epo inu rẹ si ọkọ miran.

''Lalẹ ana (ọjọ Ẹti) ni ọkọ akepo kan to gbe epo bẹntiroo lita ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn epo (33,000) danu ti a si pari dida epo rẹ sinu ọkọ miran lowurọ yi.

O ni, o ṣe ẹni laanu pe omiran danu ni tosi eleyi to ṣẹlẹ tẹlẹ''

Image copyright LASEMA
Àkọlé àwòrán LASEMA: Òjò nìkan kọ́, ọkọ̀ aképo méjì tó dànù náà ṣòkùnfà súnkẹrẹ-fàkẹrẹ l'Eko

Omọwe Femi, ọga agba LASEMA ni awọn ko ni pẹ pari dida epo rẹ ti lilọ bibọ ọkọ yoo si pada si ti tẹlẹ.

Niṣe ni ọpọ eeyan to n gba adugbo naa ha sinu sunkẹrẹ-fakẹrẹ ti awọn eeyan si ro pe ojo to rọ larọda lo ṣokunfa sunkẹrẹ-fakẹrẹ yi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionInú mi dùn pé ọmọ obinrin nìkan ni mo bi

Iṣẹlẹ didanu ọkọ epo ko jẹ tuntun nilu Eko ti a si ma saaba fa ijamba ina ti o maa n mu ẹmi ati dukia lọ.

Image copyright @lasema
Àkọlé àwòrán LASEMA: Òjò nìkan kọ́, ọkọ̀ aképo méjì tó dànù náà ṣòkùnfà súnkẹrẹ-fàkẹrẹ l'Eko

Oga agba LASEMA fi da awọn eniyan loju pe, iṣẹ gidi ti n lọ lọwọ ni ori afara Otẹdọla bayii ni eyi ti nkan ko si ni pẹ yipada.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkitiRapeCastration: ìgbésẹ̀ míì lè dẹ́kun ìwà ìfipábánilòpọ̀