Lagos: Èèyàn mẹ́rin kú l'Eko, lẹ́yìn òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá tó wó ilé mẹ́ta

Image copyright lasema

Eeyan mẹrin ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti omiyale wo ile mẹta nilu Eko.

Ninu awọn mẹrin to ku naa la ti ri abiyamọ kan ati awọn ọmọ rẹ mẹta ladugbo Magodo Iseheri.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC, ọga agba ile iṣẹ iṣẹlẹ pajawiri L'Eko Femi Osanyintolu tun fidi ọrọ mulẹ pe awọn ile meji miran mi tun wo ladugbo Ikorodu.

''Ọkan ninu awọn iṣẹlẹ yi waye ni Ita Ẹlẹwa ni Ikorodu ti ẹlẹkeeji si waye ni Agric ni Ikorodu kan naa.''

Osanyintolu ni ko si eeyan kankan to ba iṣẹlẹ mejeeji yi lọ ni Ikorodu ṣugbọn awọn ti o farakasa lawọn ribi doola ẹmi wọn ni ibẹ.

Nigba ti a beere ohun to ṣe okunfa iṣẹlẹ wọn yi, o ni oun ko le sọ pato ṣugbọn bi oju ọjọ ti ṣe ri ni nnkan ṣe pẹlu awọn ile to n wo lasiko yii.

Image copyright lasema
Image copyright rrslagos
Àkọlé àwòrán Eeyan mẹrin ni wọn lo ku ninu ile yi to wo ni Magodo

Kaakiri ilu Eko ati lawọn ipinlẹ mii lorileede Naijria ni iroyin ti n gbode nipa ọṣẹ ti arọọrọda ojo n ṣe yala nipa ẹkun omi, ile wiwo tabi afara to n ja.

Loju opo Twitter ati ayelujara niṣe ni awọn eeyan n fi aworan ijamba ti arọọrọda ojo naa n ṣe ati bi oju popo ti ṣe kun fun omi paapa julọ nilu Eko.

Ẹ le wo diẹ lara awọn aworan naa nibi.