Flooding: Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò, tí dúkìá àìmoye mílíọ̀nú naira sì bá ẹ̀kún omi lọ

Awọn eeyan Ondo Image copyright Twitter/RovingReporter

Ọjọ buruku Eṣu gbomi mu ni ọjọ Abamẹta, ọjọ Kejila oṣu Kẹwaa jẹ fun ọpọ olugbe ilu Eko atawọn ilu miran nilẹ Yoruba nigba ti arọọrọda ojo di omiyale, agbara ya ṣọọbu.

Ọpọ eeyan lo gbemi mi nigba tile wo lewọn lori, bakan naa lomi ba ọpọ dukia jẹ.

Kaakiri ilu Eko ati lawọn ipinlẹ mii lapa iwọ oorun Naijria ni arọọrọda ojo ti ṣọṣe yala nipa ẹkun omi, ile wiwo tabi afara to ja.

N ṣe lawọn eeyan fi aworan ijamba ti arọọrọda ojo naa ṣe ati bi oju popo ti kun fun omi, paapa julọ niluu Eko sori ayelujara. Diẹ ninu irufẹ aworan ọhun niyii.

Aworan yii ṣafihan ile to dawo lagbegbe Ita Ẹlẹwa ati Agric ni Ikorodu nipinlẹ Eko.

A gbọ pe ko si eeyan kankan to ba iṣẹlẹ mejeeji yi lọ ni Ikorodu.

Image copyright lasema

Eeyan mẹrin lo padanu ẹmi wọn lẹyin ti ile kan wo ladugbo Magodo Iseheri lasiko, arọọrọda ojo Satide.

Ninu awọn mẹrin to ku naa la ti ri abiyamọ kan ati awọn ọmọ rẹ mẹta

Image copyright rrslagos
Àkọlé àwòrán Eeyan mẹrin ni wọn lo ku ninu ile yi to wo ni Magodo

Opopona Marosẹ ni Lekki nipinlẹ Eko ti wọn ngba pe o jẹ adugbo awọn to ri jajẹ diẹ ni omi ti ya wọ bayii.

Ẹkun omi naa ṣe idiwọ fun ọkọ lati lọ geregee, bakan naa lo ba ọpọ dukia jẹ.

Àkọlé àwòrán Opopona Marosẹ ni Lekki ti wọn gba pe o jẹ adugbo awọn to ri jajẹ diẹ ni omi ti ya wọ bayii, kini ipin awọn adugbo mii a jẹ?
Àkọlé àwòrán Adugbo Razak Eletu ni Osapa Garden Estate ni Lekki ni agbara ojo ti gba opopona mọ awọn eeyan lọwọ yii

Adugbo Razak Eletu ni Osapa Garden Estate ni Lekki lo sọ gbogbo olugbe ibẹ di konile-o-gbele lasiko yii.

Àkọlé àwòrán Adugbo Razak Eletu ni Osapa Garden Estate ni Lekki lo sọ gbogbo olugbe ibẹ di konile-o-gbele lasiko yii

Awọn eeyan ijọba ibilẹ Waterside rawọ ẹbẹ si Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun lẹyin ti ẹkun omi ọjọ Satide gba ọna to lọ si ijọba ibilẹ naa.

Image copyright Facebook/Olufowobi Kenny
Image copyright Facebook/Olufowobi Kenny

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq lo fi aworan ẹkun omi ni ilu Ilorin sori oju opo Twitter rẹ, nibi to ti sọ pe awọn to da ilẹ sinu kọta lo n fa omiyale.

Image copyright Twitter/Abdulrahman Abdulrazaq

Ẹkun ojo ṣe bẹbẹ nipinlẹ Ondo bakan naa, koda ọkọ oju omi lawọn kan n ba wọle wọn lẹyin ti omi ti gba iwaju ile wọn tan.

Image copyright Twitter/RovingReporter
Image copyright Twitter/Ibromicah