Ọmọ ọdún méje ni mo bẹ̀rẹ̀ òwò nàbì nílé aṣẹ́wó tó tóbi jùlọ lágbàyéé
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bangladesh Brothel: Ọ̀pọ̀ àwọn àṣẹ́wó tó wà níbẹ̀ ni wọ́n bí sílé aṣẹ́wó náà

Ase airin jinna ni airi abuke ọkẹrẹ, bi eeyan ba rin jinna, yoo ri ibi ti wọn ti n fi odo ibulẹ jẹun.

Ile ti wọn ti n se owo nabi kan ree, to tobi julọ ni agbaye, to si kalẹ si orilẹede Bangladesh.

Sugbọn ọna aitọ ni wọn n gba ko awọn ọmọdebinrin wọ isẹ naa, eyi to lodi sofin.

Ọpọ awọn asẹwo to wa nibẹ ni wọn mu lọmọ ọdun meje, mọkanla, mẹẹdogun ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti ọmọ kan tilẹ pa ara rẹ, nigba ti iya rẹ fi tipa ti ọkunrin kan mọle fun, to ba ni ajọsepọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko ti wọn n ba akọroyin BBC sọrọ, ọpọ wọn lo ni inu awọn ko dun si isẹ ti awọn n se, sugbọ n ko si owo ti awọn fẹ na tawsn ba fi kuro nibẹ.

Koda, ọpọ wọn lo gba pe isẹ ti awọn n se ko dara, ti wọn si n fẹ fun awọn ọmọ wọn ni igbe aye rere to dara ju tiwọn lọ.

A tilẹ tun gbọ pe ọpọ awọn ọmọbinrin ti wọn n bi sile asẹwo naa tun ni wọn n pada fa oju wọn mọra lati ọmọ kekere si owo nabi naa.