No Bra Day: Àyájọ́ ‘Má wọ kọ́mú’ ló ń pe àkíyèsí àwọn obìnrin sí àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn

Obinrin ti ko wọ kọmu Image copyright Geneva_la_jade

Ọjọ Kẹtala osu Kẹwa ọdọọdun no ayajọ ọjọ 'Ma wọ kọmu' lorilẹede Naijiria eyi to n sọ fun awọn obinrin lati yan kọmu lodi lọjọ naa.

Gẹgẹ baa si se mọ, osu kẹwa yii kan naa ni awujọ agbaye ya sọtọ fun ayajọ gbigbogun ti aisan jẹjẹrẹ ọyan, lọwọ-lọwọ bayii, ori ayelujara si ti kun fun aworan awọ̀n obinrin to n yan kọmu lodi lonii lati dena arun jẹjẹrẹ ọyan.

Gẹgẹ baa se gbọ, ohun to fa idasilẹ ayajọ ọjọ 'Ma wọ kọmu' ni Naijiria ni lati pe akiyesi awọn obinrin si aisan jẹjẹrẹ ọyan ati awọn ọna ti wọn lee gba dena rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko ayajọ ọjọ 'Ma wọ kọmu' yii si ọpọ obiinrin maa n fi ọyan wọn silẹ bi Ọlọrun se daa, lai wọ kọmu taa mọ si Bra tabi Brassiere lati koo soke, nitori pe iwadi kan ti fidi rẹ mulẹ pe awọju kọmu gan maa n fa aisan jẹjẹrẹ.

Image copyright https://twitter.com/Trem6676

Amọ ọpọ awọn obinrin to ti ni aisan jẹjẹrẹ, amọ ti ori ti ko yọ, ni ko lee se lai ma wọ kọmu nitori wọn nilo lati fi kọmu gbe fukẹfukẹ soke, eyi ti wọn se rọpo ọmu fun wọn lẹyin isẹ abẹ ti wọn fi ge ọyan wọn kuro.

Pataki ayajọ 'Ma wọ kọmu' fawọn obinrin Naijiria:

  • Ọjọ 'Ma wọ kọmu' yii lo n seto itaniji fawọn obinrin nipa aisan jẹjẹrẹ ọyan, nitori a gbọ pe kọmu awọju gan lee fa aisan jẹjẹrẹ ọyan
  • Ọjọ yii ni wọn tun fi maa n seto ikowojọ fun isẹ iwadi lati gbogun ti aisan jẹjẹrẹ ọyan
  • Bakan naa tun ni ọjọ 'Ma wọ kọmu' wa lati ran awọn obinrin leti pe ki wọn lọ se ayẹwo ọyan wọn aibaamọ, aisan jẹjẹrẹ ti lee ba wọn ni alejo laimọ
  • Ọjọ 'Ma wọ kọmu' yoo tun jẹ ki awọn obinrin ti wọn ba tete kẹẹfin aisan jẹjhẹrẹ lara wọn lasiko ayẹwo lee tete ri itọju gba lati ka ọwọja ọsẹ aisan naa ko

Awọn igbesẹ to yẹ lati tete ka ọwọja aisan jẹjẹrẹ ọyan ko:

  • Igbesẹ akọkọ ni sise ayẹwo ọyan obinrin loore koore, paapa ni ẹkan losu kan, igba to si dara julọ lati se ayẹwo ọyan ni ọjọ kẹwa lẹyin ti obinrin ba pari nkan osu rẹ
  • Asiko ta n se ayẹwo ọyan losoosu ko gbọdọ yatọ, to si gbọdọ bara dọgba eyi ti yoo se iranwọ lati tete ri esi ayẹwo to daju
  • Awọn obinrin ti ko ba se nkan osu gbọdọ mu ọjọ kan losoosu ti wọn yoo maa se ayẹwo ọyan wọn
  • Lasiko ayẹwo osoosu yii, o mọ bi ọyan rẹ se tobi si, bo se se mulọ-mulọ si ati bi awọ rẹ se ri, eyi ti yoo jẹ ko tete mọ bi ayipada kankan ba de sara ọyan rẹ

To ba lọ se ayẹwo agọ ara rẹ nile iwosan, obinrin gbọdọ ri daju pe awọn osisẹ eleto ilera se ayẹwo ọyan fun oun lọna to peye, ti ẹnikọọkan si gbọdọ mọ baa ti se ayẹwo ọyan funra ẹni

Nibayii ti ayajọ ọjọ 'Ma wọ kọmu' tun ko loni, a n rọ gbogbo obinrin lati se ayẹwo ọyan wọn nitori ijafara lewu, ati okeere si ni oloju jinjin ti n mu ẹkun sun.