Twins Festival 2019: Àlákóso ọdún ìbejì ń fẹ́ kí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé gbárùkù ti ọdún náà

Alaafin gbe ibeji obinrin to bi lọwọ Image copyright HRM Oba Lamidi Adeyemi III

Alaafin Ọyọ Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta ti ṣe alaye pe ko si oogun kankan to n mu ki eeyan bi ibeji, yatọ si awọn ounjẹ ti a jogun ba lọwọ awọn baba wa.

Ọba Adeyẹmi ni awọn ounjẹ wonyii n ṣe anfani ti o pọ fun ọkunrin, lati ṣe ojuse rẹ lọdọ aya rẹ, lai naani ọjọ ori, pẹlu afikun pe idi niyii ti ko fi yẹ ki a gbagbe nnkan ajogunba awọn baba wa.

Alaafin ṣe alaye ọrọ naa nibi ayẹyẹ ọdun ibeji fun ọdun 2019 to waye lọjọ Abamẹta nilu Igboọra nipinlẹ Ọyọ.

Ọba Adeyẹmi, to jẹ alejo pataki nibi ayẹyẹ naa tun ṣe alaye wi pe, laye atijọ awọn baba wa maa n fi agunmu si ogi ki wọn to muu, bẹẹ si ni wọn n fi epo pupa ati ikẹtẹ jẹ iṣu to fi mọ jijẹ ilasa, ila ọrunla ati ewedu, eyi to n fun wọn lokun ati agbara gidi.

O tẹ siwaju pe, pupọ ninu awọn ogun Oyinbo ti awọn eeyan n lo, lo n ṣe akoba fun agọ ara lẹyin ti wọn ba wo aisan tan, ṣugbọn ko ri bẹẹ fun awọn ohun ibilẹ ti awọn baba wa n lo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlaafin Ọyọ: Asiri agbara bibi ibeji lọpọ igba

Lorii pataki ibeji, Kabiyesi ni wọn jẹ ẹda to ṣe pataki gẹgẹ bi awọn Yoruba ṣe kaa kun, ati pe, ara ti Ọlọrun fi ibeji da ni wi pe ile ọmọ to n bẹ ninu obinrin ko pe meji, sibẹ, obinrin n bi ọmọ meji si mẹta lẹẹkan ṣoṣo.

O tẹsiwaju wi pe, idunnu ati ayọ ni awọn ibeji maa n mu wọ gbogbo ile ti a ba ti bi wọn, idi si niyii ti gbogbo aye fi n tẹwọgba awọn ibeji gẹgẹ bii ohun arikẹ ariyọ.

Alaafin tun fi idunnu han lorii bi oore ibeji ṣe wọ akata ti ẹ naa, pẹlu alaye wi pe, idile ayọ ni idile ẹni to ba bi ibeji. Idile owo, idile itura si ni.

Ninu ọrọ ti ẹ, alaga igbimọ to ṣe eto ayẹyẹ ọdun ibeji, ẹlẹẹkeji iruẹ ti yoo waye nilu Igboọra, Olu-Aṣo Iberekodo, Ọba Adedamola Badmus ṣe alaye fun ikọ BBC Yoruba wi pe, goolu ti Ọlọrun fi ta ilu Igboọra lọọrẹ ni awọn ibeji jẹ.

O ni gbogbo ilu to n bẹ ni agbaye lo ni ohun alumọni ti ẹ, ṣugbọn ọgọọrọ ibeji ati ọmọ mẹta ni Eledua pin kan ilu naa.

Olu Aṣo wa parọwa si ijọba ati ajọ iṣọkan agbaye lati gbaruku ti ọdun naa, ko tun le goke agba sii.Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni Taye-Kehinde Oguntoye, ti o ṣe agbatẹru eto naa ṣe alaye wi pe, ilu Igboọra le di ibudo igbafẹ nla fun gbogbo agbaye ti awọn alẹnulọrọ ba le sa ipa wọn, lati ṣe ohun ti o yẹ lorii ayẹyẹ ọdun ibeji naa.

Igbagbo wọn ni wi pe ọdun naa le di ohun ti gbogbo agbaye n pe wo, ti ijọba ipinlẹ Ọyọ ati orilẹede Naijiria yoo si maa ti ibẹ pa owo gọboi.

Ọgọrọ awọn ibeji ati ọmọ mẹta lati ori awọn ọmọde titi to fi mọ awọn agbaagba lo pejupesẹ si papa iṣere ile ẹkọ Methodist ilu Igboọra nibi ti ayẹyẹ naa ti wa ye.

Lara awọn alejo pataki to darapọ mọ ipejọpọ naa ni Eleruwa ti ilu Eruwa, Ọba Samuel Adebayọ Akindele Kinni, Olu Igboọra, Ọba Jimoh Titiloye pẹlu awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ọyọ, lẹgbẹlẹgbẹ, loyeloye ati bẹẹbẹẹ lọ.