Yollywood: "Ben Murray Bruce, jọ̀ọ́ ṣàánú ajé, kó sàfihàn sinimá mí táyé ń fẹ́"

Toyin Abraham Image copyright toyin_abraham

Idi isẹ ẹni la ti n mọ ni lọlẹ, ẹni ti wọn ba si n wo, kii woran, bẹẹ ni ẹni to ba n sun, kii sun siwaju.

Idi ree ti ilumọọka osere tiata lobinrin, Toyin Abraham aya Ajeyẹmi ko se maa sun asun hanrun lẹyin igba to bimọ tuntun tan, eyi ti ko tii pe osu mẹta bayii.

Toyin tun ti wa gbe sinima tuntun kan sita eyi to pe akọle rẹ ni Elevator Baby, asiko ti oyun rẹ si pe osu mẹfa lo ya sinima naa.

Koda, sinima yii ti di wiwo lawọn ile sinima yika orilẹede yii, ti ọpọ eeyan si ti n woo fun ọgbọn ati idanilaraya.

Image copyright toyin_abraham

Sugbọn ara aje n ta Toyin Abraham lọwọ-lọwọ bayii, ti ko si tii sinmi lori bi wọn se n wo sinima naa si paapa nigba ti ibudo sinima kan kọ lati se afihan sinima Elevator Baby ọhun.

Ibudo sinima ọhun si lo jẹ ti ilumọọka sẹnetọ kan ati oludasilẹ ileesẹ amohunmaworan Silverbrds nilu Eko, Ben Murray Bruce.

Nigba to n gbarata lori isẹlẹ naa loju opo Twitter rẹ, Toyin wa n fi ohun ransẹ si Sẹnetọ Ben Bruce pe ki lo de ti gbogbo ile sinims n se afihan sinima oun ayafi ibudo sinima Murray Bruce to kọ lati se bẹẹ.

Toyin ni "Ẹ kaarọ sir. Sinima mi, #Elevatorbaby ni wọn n se afihan wọn kaakiri awsn ibudo sinima ayafi ibudo sinima tiyin nikan ni ko gbe sita. Ki lo de ti eyi fi ri bẹẹ, paapa nigba tẹ ti jẹjẹ saaju pe ẹ maa se atilẹyin fun awọn ọdọ."

Ko tan sibẹ o, Toyin tun tẹsiwaju pe ọpọ awọn ololufẹ oun lo n poungbẹ lati wo sinima naa lagbegbe Ikeja, eyi ti oun ya nigba ti oun wa ninu oyun osu mẹfa.

Image copyright toyin_abraham

O wa n rawọ ẹbẹ si Oloye Bruce lati se atilẹyin fun isẹ oun nipa sise afihan sinima naa nitori isẹ asekara ni oun se ninu sinima ọhun, ti oun si n fẹ ki oogun oju oun naa ma ja si asan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Toyin salaye siwaju pe ida ọgọjọ ninu awọn eeyan to kopa ninu sinima naa lo jẹ ọdọ ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹtadinlọgbọn lọ, ti oludari sinima naa si jẹ ọdun mẹrindinlọgbọn, ọdun mẹẹdọgbọn ati mẹrindinlsgbọn ni awọn olootu sinima naa, ti asaraloge oun si jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun pere.