Minimum Wage: NLC ní àfikún owó oṣù nìkan lẹ̀rọ̀ ìyanṣẹ́lódì

Ajọ oṣiṣẹ lorilẹ-ede Naijiria, NLC Image copyright @NLCHQ_ABUJA

Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria, NLC, ti sọ fun awọn adari ẹgbẹ ọhun lawọn ipinlẹ pe ki wọn gbaradi fun iyanṣẹlodi, bẹrẹ lati lọjọru, ọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kẹwa ọdun 2019.

Ẹgbẹ NLC ni oun yoo gunle iyaṣẹlodi naa ti ifọrọwerọ oun pẹlu ijọba apapọ ko ba so eso rere.

Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi sọwọ si awọn ẹka rẹ ni awọn ipinlẹ, ti akọwe agba ẹgbẹ, Emmanuel Ugboaja fọwọ si, l oti sisọ loju ọrọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹgbẹ NLC ni, gẹgẹ bi iwe ti oun ti kọ ṣaaju si awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni Naijiria pe, ti ajọsọ egbẹ naa pẹlu ijọba apapọ lori afikun owo oṣu ko ba so eso rere, oun yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi.

Image copyright @NLCHQ_ABUJA

Ṣaaju ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ọhun ti beere afikun owo oṣu to jẹ ida mọkanla fun awọn oṣiṣẹ to wa ni ipele keje si mẹrinla, ati afikun owo oṣu ida mẹfa abọ fun awọn oṣiṣẹ ijọba to wa ni ipele karundilogun titi de ipele kẹtadinlogun.

Ni ọjọ kẹrinla oṣu karun un ọdun 2019 ni ijọba apapọ gbe igbimọ kan dide lati boju wo afikun ti ẹgbẹ oṣiṣẹ n beere fun.

Lẹyin ọpọlọpọ ipade ati ijiroro, o jọ pe ẹ́gbẹ oṣiṣẹ ati ijọba apapọ ko tii fẹnu ọrọ naa jona.