Sanwo-Olu: Etí mi kò di sí ìrora aráàlú, ẹ fara dàá pẹ̀lú mi

Image copyright @Lag
Àkọlé àwòrán Popona Marose Ilu Eko

Akọwe agba lori ọrọ iroyin fun gomina Babajide Sanwo-Olu, Gbenga Akosile, fi ọrọ naa lede lẹyin ọpọ ipade ti gomina naa ba awọn Agbaṣẹ ṣe.

Ko din ni Agbaṣẹ ṣe bii mẹjọ ti wọn jọ fọwọ si iwe adehun lati bẹrẹ iṣẹ naa lai fi akoko ṣofo, lẹyẹ o sọka.

Gomina Ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti paṣẹ pe ko gbọdọ si koto mọ ni awọn popona ilu Eko.

Sanwo-Olu lo sọrọ yii ni opin Ọsẹ pe, bẹrẹ lati ọjọ Aje, ki awọn agbaṣẹ ṣe bẹrẹ iṣẹ ni kiakia.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionInú mi dùn pé ọmọ obinrin nìkan ni mo bi

Lara awọn agbaṣẹṣe oju- ọna naa ni Julius Berger, Hitech, Arab Contractors,Metropolitan Construction, Slavabogu,, China Construction, ati RCF Nigeria.

Image copyright Facebook
Àkọlé àwòrán Lara awon ona ti ko dara ni ilu Eko

Kete lẹyin ipade naa ni Gomina ti ni ki awọn agbaṣẹṣẹ yii lọ bẹrẹ iṣẹ atunṣe awọn opopona.

Nigba ti ikọ BBC ba Bọsun Aguda to jẹ olugbe ilu Eko sọrọ lori ipinnu ijọba, o fi idunnu rẹ han si igbesẹ yii.

O si ṣalaye pe, ọna ni koko iṣoro ti awọn eniyan Ipinlẹ Eko n koju ni pataki, awọn ti o n lo ọkọ.

Loju tirẹ Gomina Sanwo-Olu ṣẹṣẹ gbe igbesẹ to yẹ lasiko yii ni lati ṣatunṣe si awọn opopona.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDavid Adiatu oníṣẹ́ ọnà pẹ̀lú ìṣó àti òwú

Gomina Sanwo-Olu paṣẹ pe ki wọn kọkọ bẹrẹ iṣẹ pẹlu awọn popona ti o jẹ koko ti awọn eniyan maa n rin lọpọ igba lati mu adinku ba sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ.

O ni ki gbogbo awọn ile iṣẹ naa lọ ko gbogbo irin iṣẹ wọn lọ si oju ọna naa ni kiakia ki iṣẹ si bẹrẹ lẹyẹ- o- sọka.

Ninu atẹjade naa ti wọn fi ṣọwọ si awọn akọroyin ni wọn ti sọ wi pe gbogbo eto ti to lati ri i pe iṣẹ bẹrẹ ni awọn ibi pataki ni ipinlẹ Eko.

Nibo ni iṣẹ atunṣe opopona ti fẹ bẹrẹ ni Eko?

Sanwo Olu wa fi da awọn eniyan loju pe ajọ ti n ri si igbokegbodo ọkọ ni Eko [LASMA] yoo maa ṣiṣẹ tọsan toru lati mu irinna ọkọ rọrun.

Olubadamọnran fun gomina naa lori ọrọ iṣẹ ati akanṣe, Aramide Adeyoye ṣalaye lori awọn opopona ti iṣẹ wọn yoo gunle bii Ojota ti o gba Ikorodu ati Kudirat Abiola kọja.

Awọn yooku ni marosẹ Apọngbọn, Babs Animaṣahun, Agric/Ishawo ati Ijẹdẹ ni ọna Ikorodu, to fi mọ popona Marosẹ Lekki-Epe lati Abraham Adesanya si Orita Eleko.

Ti wọn yoo tun ṣe iṣẹ ọna naa de Ikoyi, ile-igbe Ijọba ni Ikeja ati Victoria Island.

Sanwo-Olu fẹ́ ṣàtúnṣe òpópónà 116, ọ̀pọ̀ aráàlú ń fẹ́ kí àtúnṣe ọ̀nà dé àdúgbò wọn:

N ṣe lawọn eeyan ilu Eko ti bẹrẹ si ni rawọ ẹbẹ si Gomina ipinlẹ naa pe, ko nawọ atunṣe opopona to fẹ bẹrẹ lọjọ Aje oni de ọdọ wọn.

Loju opo Twitter, ni wọn fi arọwa wọn yii sọwọ si gomina, lẹyin ti ijọba Eko ni oun ṣetan lati koju ipenija oju ọna to pakasọ nilu naa.

Image copyright @Ijobaoflagos

Ninu ikede to fi sita bakan naa, Sanwo-Olu ni opopona bii mẹrindinlọgọfa ni yoo gba atunse yatọ̀ si igba oju ọna ti wọn ti tun se tẹlẹ laarin osu mẹta sẹyin.

Gomina Eko ni eti oun ko di si irora tawọn olugbe ipinlẹ Eko n la kọja lasiko ojo arọọrọda yii, to si rọ awọn araalu lati fara daa pẹlu ijọba, nibayii to n se aayan lati bu tutu si oju egbo naa.

Image copyright @jimidisu

Lẹnu ọjọ mẹta yii, wahala sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ nilu Eko fẹ lekenka, ti awọn awakọ ati arinrinajo si n ke irora nipa idiwọ ti awọn ọna to bajẹ wọn yii n fa.

Adugbo ti awọn eniyan ti n sọ niyi:

Ni meni meji ni onikaluku bẹrẹ si ni tọka adugbo wọn, ti wọn si n beere ki ijọba nawọ atunṣe de ọdọ tawọn naa, nitori tẹni ba dakẹ, tara rẹ yoo ba dakẹ ni.

Lọjọ Aiku ni Gomina Sanwo Olu fi ikede si oju opo Twitter rẹ pe, asiko to bayi lati koju ipenija awọn oju ọna Eko to nilo atunṣe.

O ni lẹyin ipade toun ṣe pẹlu awọn agbaṣẹse to n tun ọna ṣe, awọn yoo ri pe iṣẹ to peye waye lori awọn oju ọna to bajẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: