NigeriaRoadAccident- Ọkọ àjàgbé kọlu obìnrin kan lórí ọkadá ó sì kú

oko ajagbe Image copyright @LAM
Àkọlé àwòrán Ijamba oko Ajagbe

Ọmọbinrin kan ni o ti gbekuru jẹ lọwọ ẹbọra lataari ijamba ọkọ Ajagbe ti o rọlu ọkada rẹ ni Abẹokuta.

Olori Ajọ Ẹṣọ Oju Popo (FRSC) ẹka ti Sango-Ota ni Ipinlẹ Ogun, Akeem Ganiyu ni o fi ọrọ naa lede.

O ni ọkọ Ajagbe naa pẹlu nọmba ọkọ XC 791 LSR, ti o n lọ si Ipinlẹ Eko lati Abeokuta ni o deede padanu ijanu ọkọ rẹ, ti o si ṣeku pa ọmọbinrin naa.

Ganiyu ṣalaye pe eniyan mẹta ni ọkọ ajagbe naa ṣe akolu si ṣugbọn ti eniyan kan si gbẹmi mii loju ẹsẹ.

Ọkọ Ajagbe naa lo kọlu ọkọ ayọkẹlẹ meji ti awọn ti o wa ninu ọkọ naa si fara pa ṣugbọn ti o da ẹmi arabinrin naa legbodo.

Ni bayii, oku arabinrin naa ni wọn ti gbe lọ si ile igbokupamọsi ti ile iwosan gbogboogbo Ijọba ni Ifọ, Ipinlẹ Ogun.

Bawo ni ijamba naa ṣe ṣẹlẹ?

Nigba ti o n ba ikọ BBC sọrọ, olori ajọ alaabo oju popo (FRSC), Ọladele Clement, ṣalaye pe ọkọ ajagbe naa ni o ti wa ni ahamọ ajọ naa.

O tẹsiwaju pe, pupọ ninu awọn ijamba yii lo n ṣẹlẹ lataari aini suuru awọn awakọ.

O ni awọn ọlọkada gbọdọ maa fi suuru rin lasiko ojo yii paapaa ti ọpọ opopona ko dara mọ bayii.

Oladele ni wi pe awọn ọna wọnyii ni wọn n ṣe lọwọṣugbọn ti aini suuru pupọ awọn awakọ yii lo n fa ijamba ba awọn ẹlomiran.

Ninu alaye rẹ lo ti mẹnu baa wi pe, ọpọ ọkọ ni abẹbẹ oju gilaasi [wiper] wọn ko dara to lasiko ojo ti wọn ko de riran ri ọkọ to n bọ daada.

O wa gba awọn awakọ ni imọran lati ya patapata kuro ni oju popo nigba ti wọn ko ba le tẹsiwaju mọninu irin ajo.

Clement mẹnuba ba pe, yiya ọkọ silẹ lojiji naa maa n ṣe okunfa ijamba ti o si le mu ẹmi dani.

Ganiyu, ti o jẹ olori ẹka ti Sango Ota naa wa rọ awọn ọlọkọda lati maa lo koto-adabori ki wọn si maa din ere sisa ku lati dẹkun gbigba ori mọlẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTwin Festival 2019: Ṣé ọbẹ ìlasa àti àmàlà ló ń ṣokùnfà bíbí ìbejì ní ìlú Igboọrà?
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkitiRapeCastration: ìgbésẹ̀ míì lè dẹ́kun ìwà ìfipábánilòpọ̀