Kayode Abiara: Ọmọ Nàíjíríà, ẹ má ba ọkàn jẹ́ lórí ààbò tó mẹ́hẹ, ewu ìgbà ìkẹyìn ló jẹ́

Kayode Abiara: Ọmọ Nàíjíríà, ẹ má ba ọkàn jẹ́ lórí ààbò tó mẹ́hẹ, ewu ìgbà ìkẹyìn ló jẹ́

Odu ni Wolii Samuel Kayọde Abiara laarin awọn ojisẹ Ọlọrun lorilẹede Naijiria, kii si se aimọ fun oloko awọn ọmọ orilẹede Naijiria.

Lasiko ti ilumọọka ojisẹ Ọlọrun naa si n ba BBC Yoruba sọrọ lori aifararọ eto aabo lorilẹede Naijiria, Abiara salaye pe, kii se orilẹede Naijiria nikan ni eto aabo ti mẹhẹ, kaakiri awọn orilẹede lagbaye ni.

O ni eyi ri bẹẹ tori igba ikẹyin la wa yii, tii se igba ewu ti ole, ipaniyan, ogun, ọtẹ ati iwa ika too gbilẹ pupọ gẹgẹ bi asọtẹlẹ ti wa nipa wọn ninu iwe mimọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n sọ ero ọkan rẹ nipa awọn ojisẹ Ọlọrun to ni Oluwa lo sọ fun awọn lati dibo gẹgẹ bii aarẹ Naijiria, Abiara ni o seese ko jẹ ero ọkan wọn tabi ki Ọlọrun pasẹ fun wọn lootọ lati lọ dibo aarẹ.

O fikun pe nigba miran, ọrọ Oluwa lee ma wa si imusẹ logun ọdun, to si seese ki eyi sokunfa bi awsn eeyan yoo se si irufẹ ojisẹ Ọlọrun naa gbọ.

O wa rọ awọn araalu lati mase tabuku awọn ileewe tawọn ijọ ẹlẹsin da silẹ pe owo wọn ti wọn ju, o ni ọbẹ to dun, owo lo paa, bẹẹ si ni ọpọ awọn ileewe ẹlẹsin naa lo n se iranwọ ẹkọ ọfẹ fun awọn ọmọ alaini.

Ẹ wo fidio yii, lati gbọ ẹkunrẹrẹ ohun ti Wolii Kayọde Abiara sọ nipa ipo ti orilẹede Naijiria wa ati imọran to ni fun ijọba pẹlu araalu.