Aisha Buhari: Ọ̀pọ̀ aráàlú ní Aisha ti pariwo ṣáájú pé Buhari kọ ló ń darí ìjọba

Aisha Buhari Image copyright @aishambuhari

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n sọ ero ọkan wọn lori aawọ to n waye nile ijọba nilu Abuja laarin aya aarẹ, Aisha Buhari ati Mamman Daura.

Aawọ naa, to n ja rainrain lori ayelujara lo da lori fidio kan to lu sita lati ọdọ ọmọ Daura, Fatimọ, eyi to se afihan Aisha to n pariwo pe wọn n gbo oun lẹnu.

Aisha ati Fatimọ si ni wọn ti salaye ohun to kan wọn nipa fidio naa, ti ọkọọkan wọn si n naka aleebu si ara wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ nigba ti wọn n da si ọrọ yii, oniruuru ero ni awọn ọmọ Naijiria fi han nipa isẹlẹ naa.

Kayode Ogundamisi@ogundamisi ni bi fatimah se gba lootọ ni oun ya aya aarẹ nibi to ti n pariwo ni bonkẹlẹ kii se nkan kekere rara, o ti tapa si ofin eto aabo, o si yẹ ki aarẹ lee to ile rẹ.

@YoungOtutu, o ni lẹyin gbogbo atotonu yii, ẹ jẹ ka se agbẹyẹwo ọrọ awọn mejeeji, ta si lee sọ pe aarẹ Buhari ti kuna ni gbogbo ọna.

@ayemojubar, oun ni to ba jẹ pe Fatimah, ọmọ Daura ni ọkan lati gbena woju Aisha ati awọn agbofinro, ti Buhari ko si ri ohunkohun se si, ka ma sẹsẹ sọ Buhari gan funra rẹ, a jẹ pe ohun ara lo n sẹlẹ nile ijọba ni Abuja.

@dbola01 lero tiẹ ni ọjọ p ti Aisha ti n pariwo pe kii se Buhari lo n se akoso ijọba, to si darukọ Mamman Daura.

@onos_147 ni to ba jẹ ọmọ ipinlẹ Edo ni Aisha ni, Fatimah ko ba ti ge ni imu. Iranu!

Daura kò tan mọ́ Buhari àmọ́ òun àti ọmọ rẹ̀ ti fẹ́ ba ẹbí mi jẹ́ - Aisha figbe ta

Ni ọjọ Aje ni iroyin ifọrọwanilẹnuwo kan ti iyawo aarẹ, Aisha Buhari ati Fatimah, ọmọ Daura to jẹ bi ẹgbọn fun Buhari ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC gbode kan lori ayelujara.

Ko si si idi meji bikose bi fidio kan, ninu eyi ti aya aarẹ ti n lọgun tantan se bọ sori ayelujara lọjọ Ẹti.

Image copyright @aishambuhari

Lọwọ yii, Aisha to jẹ aya aarẹ Muhammadu Buhari ti n ke gbajare pe, awọn ẹbi Daura ko tan mọ ọkọ oun o, ṣugbọn wọn ti fẹ fa ẹbi oun ni itan ya.

Gẹgẹ bii ọrọ rẹ, Aisha ninu fidio ti a n sọrọ rẹ yii, n lọgun too pe ki wọn si ilẹkun fun oun lati wọle, lẹyin ti Buhari ti paṣẹ pe ki wọn fi ile onigilaasi naa silẹ fun Yusuf ọmọ oun, amọ yẹyẹ ni Fatimah to jẹ ọmọ Daura n fi oun ṣe.

Image copyright @aishambuhari

Kii ṣe iroyin mọ pe, ọpọ onwoye lo ti n fi ẹsun kan Mamman Daura, to jẹ baba Fatimah pe oun atawọn eeyan kan lo ti joye alagbara, to ti gba agbara lọwọ aarẹ Buhari, ti wọn si n tukọ Naijiria labẹ aṣọ.

Nibayii, Aisha ti wa se bi ẹni fi idi ahesọ ọrọ yii mulẹ ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, eyi to ti fi ẹsun kan awọn agbofinro ati ẹsọ rẹ pe wọn n wo gbogbo bi Fatimah ṣe ṣe si oun.

Image copyright @aishambuhari

Sugbọn awọn agbofinro naa ko lee ṣe ohunkohun nipa rẹ nitori pe ẹni ti aje ọrọ naa ṣi mọ lori jẹ ọmọ Mamman Daura.

Fatimah funra rẹ fi ọrọ mulẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo tirẹ pe, awo ọjọ pipẹ ni baba oun, iyẹn Mamman Daura pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari, ti ẹnikẹni ko si lee ri aarin wọn.

Ni bayii, ọpọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ati ọlọgbajọgba ni wọn ti jade lati wi tẹnu wọn lori ọrọ yii.

Bi awọn ẹgbẹ ajafẹtọ bii Coalition in Defence of Nigerian Democracy and Constitution, CDNDC ṣe n lọgun pe, aṣilo ipo lo n da aarẹ Buhari laamu, bi bẹẹ kọ, ko laṣẹ lati gbe ile ijọba kalẹ fun Mamman Daura.

Civil Society Network Against Corruption, CSNAP naa n pariwo pe ohun to han gbangba pẹlu ohun to n ṣẹlẹ bii sinima laarin ẹbi aarẹ Buhari yii n fihan pe, Daura gan an ni alakoso orilẹede Naijiria labẹ aṣọ.