New minimum wage: Ìjọba àpapọ̀, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yóò ṣèpàdé lónìí lórí owó oṣù tuntun

Iwọde awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ Image copyright AFP

Loni, ọjọ Iṣẹgun, ọjọ karundinlogun oṣu kẹwa ọdun 2019 ni ipade manigbagbe kan yoo waye laarin ijọba apapọ ati ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria lati lee yanju wahala to n suyọ lori sisan owo oṣu tuntun to kereju fawọn oṣiṣẹ ati atunto owo osu awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria.

Ni ọjọ Aiku ni ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria, gbe atẹjade sita ninu eyi ti wọn ti kilọ fun ijọba apapọ pe bi ko ba tete wa wọrọkọ fi ṣada lori sisan owo oṣu tuntun naa atawọn atunto akasọ owo oṣu gbogbo to kan, iyanṣẹlodi lo kan ti awọn yoo sa di.

Eeyan meji ku nibi iwọde DR Congo

'Ẹnu lásán kò lè sàn owó oṣu oṣiṣẹ l'Ekiti'

Philomina nikan kọ lo ṣe magomago owo JAMB

Ìjọba àpapọ̀ kò leè ṣùn torí ìyanṣẹ́lódì òṣìṣẹ́ tó ń bọ̀

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEjo abami to n mu owo ni ajọ Jambu

Lọna ati dena iyanṣẹlodi naa lo mu ki ijọba apapọ, nipasẹ minisita fọrọ oṣiṣẹ, Chris Ngige o pe ipade fun ifikunlukun lori rẹ ni ọjọ Iṣẹgun.

Bi o tilẹ jẹ pe ijọba apapọ n ṣalaye pe gbogbo ipa to yẹ ni sisa ni awọn ti sa ṣugbọn ti ẹgbẹ oṣiṣẹ naa ṣi n wi ohun miran.

Ninu ọrọ to sọ ṣaaju ipade naa ti yoo waye loni nilu Abuja, minisita fun ọrọ oṣiṣẹ Chris Ngige fohun silẹ pe o wu ijọba lati wa ojuutu si ọrọ ẹkunwo oṣu oṣiṣẹ naaki o to di oṣu kọkanla ọdun lati fi aye silẹ fun sisan owo osu tuntun naa ni irọwọ-rọsẹ.

Image copyright Getty Images

O ni ipade ọjọ iṣẹgun ni yoo sọ ibi ti wọn yoo fi okun si lori ọrọ owo oṣu tuntun naa.

Amọṣa, ẹgbẹ oṣiṣẹ ni ipade naa, ni ero tawọn, ṣe pataki fun aṣeyọri lori ọrọ owo oṣu tuntun naa.