Mama Rainbow pe 77 lónìí, àwọn òṣèré tíátà kọrin re kìí
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Mama Rainbow: Toyin Adegbola àti Razak Olayiwola ní ìyá rere àti àwòkọ́ṣe gidi ní

Arise ni arika, arika si ni baba iregun, ohun taa ba si se loni, yoo di itan to ba di ọla.

Bẹẹ ni ọrọ ri fun ilumọọka osere tiata Yoruba lobinrin, Esther Idowu Phillips taa mọ si Mama Rainbow, ẹni to pe ọdun mẹtadinlọgọrin loke eepẹ loni.

Lasiko ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, ọpọ osere tiata lọkunrin lobinrin si lo n kọrin rere ki agba osere naa pe iya daada ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Toyin Adegbọla, taa mọ si Asẹwo to re Mecca salaye pe, aya gidi ati iya rere ni Mama Rainbow jẹ, to si maa n gba eeyan ni imọran nipa bi sjọ iwaju yoo se dara, ti kii si kanra mọ ẹnikẹni.

Tunwẹ, Razak Ọlayiwọla, tawọn eeyan mọ si Ojopagogo naa salaye pe asẹwo ati ajẹ ni iya naa nitori pe gbogbo ọkunrin lo maa n pe ni ọkọ oun, to si tun maa n gba eeyan nimọran, bii ẹni to mọ ohun ti yoo sẹlẹ lọjọ ọla.

Ileesẹ kan, Gulf Platform si ti seto bi wọn yoo ti se ayẹyẹ ọjọ ibi agba osere ọhun nilu Dubai.

Juliana Afọnrewo, tii se ọkan lara oludari ileesẹ naa ni awọn seto naa fun Mama Rainbow nitori ohun to dara ni lati se ajọyọ awọn osere wa nigba ti wọn wa laaye.