Aisha Buhari: Aya ààrẹ tọrọ àforíjìn lórí fídìo tó ti fi ìbínú sọ̀rọ̀

Aisha Buhari Image copyright Faceboo/Aisha Buhari
Àkọlé àwòrán Aisha Buhari: Aya ààrẹ tọrọ àforíjì lórí fídìo tó ti fi ìbínú sọ̀rọ̀

Aisha Buhari ti tọrọ aforijin lori fọnran ti Fatima to jẹ ọmọ ibatan Aarẹ Muhammadu Buhari, Mamman Daura fi sita.

Aisha tọrọ aforijin lọwọ awọn ọmọ rẹ, ẹbi atawọn ọmọ Naijiria fun itiju ti fọnran naa mu wa.

Fọnran naa fihan bi iyawo aarẹ, Aisha Buhari ṣe fariga pe wọ́n tilẹkun mọ oun ninu ile ijọba to wa l'Abuja pẹlu bi awọn aṣọna si ṣe wa ninu ile ṣi n tu ọrọ sita kaakiri itakun ayelujara Taló ya fídíò ibi tí Aisha Buhari ti ń bínú ní Aso Rock?.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Hausa, iyaafin Buhari ni lootọ oun lo wa ninu fidio naa toun n fi ibinu sọrọ.

Ninu fidio ọhun, Aisha Buhari n pariwo pe ki ẹbi Daura ko kuro ni ile ti wọn fun wọn gbe ninu Aso Rock.

Image copyright Mamman Daura
Àkọlé àwòrán Mamman Daura

Ṣugbọn o ni fọnran naa kii ṣe ti ọdun yii rara ninu eyi to ti n fesi si awọn ẹbi Daura pe wọn ko jẹ ki oun wọ inu 'ile onidigi' (Glass house villa), Fatima si lo ya fidio naa.

Ninu atẹjade kan ti adari eto iroyin fun aya Aarẹ Naijiria, Ọgbẹni Suleiman Haruna fi sita lorukọ Aisha lo ti bẹbẹ fun idarijin.

Aya aarẹ fọrọ yii lede nigba tawọn iyawo gomina ipinlẹ mẹrẹẹrindinlọgbọn ṣabẹwo si i nile ijọba.

Aisha ni Fatima ya fọnran naa lati le doju ti oun ni, ati pe ihuwasi ẹbi Daura ko ṣẹyin bi aarẹ Buhari ṣe ni ki wọn kẹru wọn kuro nile ijọba.