Funke Adesiyan: Gbajúgbajà òṣèré Yollywood di olùrànlọ́wọ́ aya ààrẹ, Aisha Buhari

Funke Adesiyan Image copyright Facebook/Funke Adesiyan
Àkọlé àwòrán Funke Adesiyan, òṣèré Yollywood tó di olùrànlọ́wọ́ aya ààrẹ, Aisha Buhari

Oṣere Yollywood, Funke Adesiyan ti di oluranlọwọ aya Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Aisha Buhari lori ọrọ abẹle ati awujọ.

Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu iyansipo rẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn oluran lọwọ tuntun lofiisi aya aarẹ.

Lọsẹ to lọ ni Aisha pada silu Abuja lẹyin to ti wa nilẹ okere fun bi oṣu mẹta.

Ọjọ meji lẹyin tawọn kan n gbe iroyin ofege pe aarẹ Buhari fẹ ṣegbeyawo pẹlu obinrin mii ni Aisha pada si orilẹ-ede Naijiria.

Ta ni Funke Adesiyan?

Ọjọ kẹrinla, oṣu kẹta ni ọjọ ibi oṣere Funke Adesiyan, ọmọ ilu Ibadan nipinlẹ Oyo nii ṣe.

Funkẹ kọ ẹkọ nipa ere itage ni Fasiti Olabisi Onabanjo, bakan naa lo gboye Diploma ninu imọ ofin nile iwe yii kan naa.

Gbajugbaja oṣere Yoruba ni Funkẹ Adesiyan, o si wa lara awọn oṣere ti Eleduwa fun lẹbun ere ṣiṣe lagbo awọn oṣere.

Image copyright Facebook/Funke Adesiyan
Àkọlé àwòrán Ọjọ kẹrinla, oṣu kẹta ni ọjọ ibi oṣere Funke Adesiyan, ọmọ ilu Ibadan nipinlẹ Oyo nii ṣe.

Ni kekere lọwọ rẹ ti ji sowo, koda ọmọ ọdun mọkandinlogun lo wa nigba to kọ ile akọkọ rẹ.

Iroyin kan tiẹ sọ pe ọmọ ọdun mẹtadinlogun lo wa nigba ti o ṣiṣẹ ni miliọnu kan naira lọwọ.

Ibẹrẹ aye Funke Adesiyan

Funke Adesiyan bẹrẹ pẹlu iṣẹ arinrin oge ni ọmọ ọdun mẹtala, o bẹrẹ si ni ṣe okowo fun ra rẹ, nigba to pe ọmọ ọdun mẹrinla.

O bẹrẹ si ni ṣe oṣelu lọmọdun mẹẹdọgbọn, nigba naa lo ṣe ipolongo fun oludije fun ipo aarẹ, Mallam Ibrahim Shekarau.

Idibo gboogbo ọdun 2011 lorilẹ-ede Naijiria ni Shekarau ti dije fun ipo aarẹ, bakan naa lo si ti jẹ gomina ipinlẹ Kano ri.

Bi Funke Adesiyan ti wọ agbo oṣelu ree

Lẹyin ti Funkẹ bẹrẹ oloṣelu, lo sọ erongba rẹ lati ṣoju Ẹkun Ila Oorun Guusu Ibadan nile igbimọ aṣofin Ipinlẹ Oyo ninu eto idibo ọdun 2015.

O jawe olubori ninu idibo abẹle ṣugbọn o fidi rẹmi ninu ibo gangan an ninu eyi to ti padanu ọpọ owo ati ohun ini rẹ.

Amọ, Funkẹ ya ọpọ eeyan lẹnu nigba ti o pe apejẹ lati dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ.

Lori ohun to wa laarin rẹ ati Saheed Balogun

Funkẹ ni lootọ ni oṣere Saheed Balogun ti jẹ ololufẹ oun ri, o ni oun nifẹ Saheed nitori oun rii gẹgẹ bi oninukan eeyan nigba naa.

O fikun ọrọ rẹ pe akitiyan Saheed lati ran awọn to ba ni iṣoro kan tabi omiiran lọwọ wa lara awọn ohun to jẹ ki oun nifẹ rẹ.

Amọ, onikaluku lọ lọna tirẹ lẹyin ti oun ri ihuwasi to yatọ ninu ihuwasi Saheed.