NLC: Àwa àti ìjọba àpapọ̀ tí ṣé tiwá ó kù sọwọ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ láti yanjú tiwọn

Festus Keyamo ati Chris Ngige Image copyright @fkeyamo
Àkọlé àwòrán Afikun owo oṣu yii lo waye lẹyin ọgọsan an ọjọ ti ijọba buwọ lu abadofin afinkun owo oṣu tuntun

Ijọba gbọdọ bẹrẹ si ni san afikun owo oṣu tuntun fun oṣiṣẹ bẹrẹ láti oṣu kẹrin ọdun yí.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria lo salaye ọrọ yi ninu ifọrọwanilnuwo pẹlu BBC Yoruba.

Issa Aremu to jẹ akọwe apapọ ẹgbẹ awọn Textile and Tailoring Union (NUTGTWN) to si wa lara awọn to kọwọrin pẹlu aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ ninu idunadura pẹlu ijọba lo sọrọ yi.

O ni lootọ ni awọn ko ri ohun to wu awọn gba lọdọ ijọba gẹgẹ bi afikun ṣugbọn eyi tawọn ṣe yi yoo mu iyipada ba igbe aye awọn oṣiṣẹ Naijiria.

O ni nipele nipele ni afinku to ba owo oṣiṣẹ.

''Awọn to wa ni ipele keje yoo gba to alekun ida mẹtalelogun ninu ọgọrun ti awọn to wa loke patapata yoo gba to alekun ida mẹwa ninu ida ọgọrun''

Aremu tẹsiwaju pe bayi ti awọn ti pari eto pẹlu ijọba apapọ, ohun to ku ni ki awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ati awọn ijọba ipinlẹ ati ibilẹ naa joko lati ṣayẹwo afikun to ba yẹ.

''Inu wa dun pe awọn ijọba ipinlẹ kan bi ipinlẹ Eko ni awọn yoo san ju ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira lọ foṣiṣẹ.Iru nkan bayi laa n fẹ lọdọ awọn ijọba ipinlẹ.''

Bi a ko ba gbagbe,mọjumọ ọjọ Ẹti lẹgbẹ oṣiṣẹ ati ijọba apapọ kede pe awọn ti fẹnuko lori afikun owo oṣu oṣiṣẹ.

Idunadura naa ti bẹrẹ lati nnkan bi oṣu mẹrin sẹyin ti ijọba ti kọkọ kede pe ohun yoo fikun owo oṣu oṣiṣẹ Naijiria.

Image copyright Google
Àkọlé àwòrán O ni nipele nipele ni afinku to ba owo oṣiṣẹ.

Bi wọn ti ṣe fẹnuko si afikun owo oṣu oṣiṣẹ

Lẹyin ọpọlọpọ ijiroro, ijọba apapọ ati ẹgbẹ oṣiṣẹ ti fẹnuko lori afikun owo oṣu oṣiṣẹ ni Naijiria.

Minisita abẹlẹ fun iṣẹ ati igbanisiṣẹ, Festus Keyamo lo fi ọrọ naa lede loju opo Twitter rẹ.

Keyamo sọ ninu ọrọ naa pe, "Lẹyin ijiroro laarin ijọba apapọ ati ẹgbẹ oṣiṣẹ, a ti fẹnu ko lori afikun owo oṣu oṣiṣẹ, a ti bẹrẹ iṣẹ lori afikun owo oṣu ọhun."

Afikun yii lo waye lẹyin ọpọlọpọ atotonu to waye larin ijọba ati ẹgbẹ oṣiṣẹ, lẹyin ti ijọba apapọ buwọlu ẹgbẹrun un lọna ọgbọn owo ọsu oṣiṣẹ to kere julọ Ìná ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC ati ìjọba kò wọ̀ níbi ìpadé .

Akọwe gbogboogbo fun ẹgbẹ Trade Union Congress, Musa-Lawal Ozigi, fi idi ọrọ naa mulẹ, o si gboriyin fun ijọba apapọ ni bi o ṣe fọwọ si afikun owo oṣu ọhun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTi o bá dá ara ẹ lójú, ki ẹni tó n ṣe irun kí n gbọ́?

Ninu tuntun yii, awọn oṣiṣẹ to wa ni ipele keje yoo ni afikun ida mẹtalelogun ninu ọgọrun un owo oṣu, bẹẹ naa ni awọn oṣiṣẹ ni ipele kẹjọ yoo ni afikun ida ogun.

Bakan naa ni awọn oṣiṣẹ to wa ni ipele kẹsan an yoo ni afikun ida mọkandinlogun ninu ida ọgọrun un ninu owo oṣu.

Nigba ti awọn to wa ipele kẹwaa si mẹrinla yoo ṣe ni afikun ida mẹrindinlogun ninu ida ọgọrun un, ni awọn to wa ni ipele kẹẹdogun si ipele kẹtadinlogun yoo ṣe ni afikun ida mẹrinla owo oṣu.

Image copyright @OmasoroO
Àkọlé àwòrán Minimum wage: Ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ti fẹnukò lórí àfikún owó oṣù tuntun- Keyamo

Ifẹnuko lori owo oṣu yii ko rọrun rara fun ẹgbẹ oṣiṣẹ, nitori ọpọlọpọ ipade lo ti waye laarin ijọba apapọ ati ẹgbẹ ọhun, sugbọn ti ko so eso rere.

Afinkun owo oṣu yii lo waye lẹyin ọgọsan an ọjọ ti aarẹ Muhammamdu Buhari buwọ lu abadofin afinkun owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ.