BBC 100 Women 2019: Wo àwọn ọmọ Afirika tó wà nínú wọn

Images of many of the BBC's 100 Women 2019
Àkọlé àwòrán Awọn obinrin ọhun ni BBC yẹ si lẹyin ti wọn ṣe iṣẹ takuntakun lorilẹ-ede wọn

Ileeṣẹ BBC ti ṣe afihan awọn obinrin to dantọ ju lagbaye fun ọdun 2019.

Awọn obinrin naa ni ileeṣẹ BBC ni wọn ti ṣe ohun to lami-laaka to si tọ ki wọn yẹ wọn si lagbaye.

Lara wọn ni awọn oniroyin, awọn olorin, awọn ọga agba ile iṣẹ, awọn aṣofin, awọn omuwẹ, ati bẹbẹ lọ.

Pupọ lara awọn obinrin ọhun lo jẹ ọmọ ilẹ Adulawọ ti wọn ti ṣe iṣe takuntakun lorilẹ-ede wọn.

A fẹ wo diẹ lara awọn ọbinrin ọhun to jẹ ọmọ ilẹ Adulawọ.

1. Kalista Sy - Onkọwe ati olootu sinima ni Senegal

Kalista lo kọ ara rẹ bi wọn ṣe n kọ itan sinima, lẹyin naa lo gbe sinima ti akọle rẹ n jẹ Mistress jade, leyi to lami-laaka lorilẹ-ede rẹ ni ibẹrẹ ọdun yii.

Sinima ọhun sọ nipa awọn obinrin ilẹ Afirika to tiraka lati sọriire lai ta ara wọn lọpọ fun awọn okunrin.

Sinima naa si tun sọ nipa ohun toju obinrin n ri nile adulawọ, paapa awọn to wa lati idile olorogun ati ọrọ to jẹ mọ ilera obinrin.

Igbagbọ Kalista ni pe, awọn obinrin lee di ẹni pataki lawujọ, lai ni i fi ṣe ohun toju wọn n ri nilẹ adulawọ.

2. Benedicte Mundele - oniṣowo ounjẹ ni DR Congo

Image copyright @benesthermunde1
Àkọlé àwòrán Benedicte gbagbọ pe, ọpọlọpọ anfani lo wa niniu ohun ti ọpọ eeyan mii n wo bi iṣoro

Benedite jẹ oniṣowo ounjẹ ati eso ọgbin lorilẹ-ede rẹ, Democratic Republic of Congo.

Oun ni oludasilẹ Suprise Tropical, illẹsẹ ti wọn ti n ta ounjẹ ajẹpọnula ati eleyii ti eeyan lee gbe rele, ni Kinshasha.

Igbagbọ Benedicte ni pe, ọpọlọpọ anfaani lo wa niniu ohun ti ọpọ eeyan mii n wo bi iṣoro.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPainter: Samuel ni ìdàgbàsókè Nàìjíríà ló jẹ òun lógún!

3. Farida Osman - Omuwẹ lati orilẹ-ede Egypt

Lọdun 2017 ni Farida di obinrin akọkọ lorilẹ-ede Egypt, nigba to gba ami ẹyẹ ninu idije awọn omuwẹ FINA World Aquatics Championships.

Farida lee wẹ to bẹẹ gẹ, ti wọn fi n pe ni " Ẹja alawọ wura" ni orilẹ-ede rẹ.

O jẹ ẹni to ma n ba ọpọ awọn akẹkọ Fasiti sọro lati ru wọn soke fun aṣeyọri to peye.

Afojusun farida ni lati gba ami gẹgẹ omuwẹ to pegede julọ ni idije Olympi ti yoo waye ni Tokyo lọdun 2020.

4. Rana El Kaliouby - Onimọ ẹrọ kọmputa ni Egypt:

Rana El Kaliouby jẹ ọkan lara awọn onimọ ẹrọ kọmputa to pegede julọ lorilẹ-ede Egypt.

Oun ni oludasilẹ ileeṣe ti wọn ti pilẹ ẹrọ "Affectiva," eyi to lee mọ bi eeyan ṣe n ni imọlara si.

Lara awọn ẹrọ kọmputa ti Kaliouby pilẹ rẹ ni wọn n lo ninu ọkọ lati mọ awọn awakọ to ba n sun nigba ti wọn ba n wa ọkọ loju popo.

Igbagbọ Kaliouby ni pe, ko si ohun ti okunrin le ṣe, ti obinrin ko le ṣe jubẹ lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKayode Abiara: Ọmọ Nàíjíríà, ẹ má ba ọkàn jẹ́ lórí ààbò tó mẹ́hẹ, ewu ìgbà ìkẹyìn ló jẹ́

5. Ahlam Khudr - Adari ifẹhonuhan ni Sudan

Nibi ifẹhonuhan kan lọdun 2013 ni wọn ti ṣeku pa ọmọ Ahlam, to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun nigba naa.

Lẹyin iṣẹlẹ yii ni Ahlam ti ṣeleri lati mu ki ijọba fi imu awọn to pa ọmọ rẹ danrin, to si ti n pe ara rẹ ni iya fun gbogbo awon ti wọn ti ṣeku pa ni Sudan.

Lati ọdun naa ni obinrin yii ti di jijangbara fun awọn ti wọn n pa lona aitọ ati awọn to deede di awati lorilẹ-ede Sudan.

Ahlam ti jẹ ọpọlopọ iya nibi ifẹhonuhan lodi si ijọba orilẹ-ede rẹ, paapa julọ nibi ifẹhonuhan lodi si ijọba aarẹ ana lorilẹ-ede ọhun, Omar al-Bashir.

Igbagbọ Ahlam ni, orilẹ-ede Sudan si maa goke agba lawujọ agbaye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBangladesh Brothel: Ọ̀pọ̀ àwọn àṣẹ́wó tó wà níbẹ̀ ni wọ́n bí sílé aṣẹ́wó náà