Ghana Floods: Omiyalé ní Ghana, èèyàn 28 dolóògbé!

omiyale

Oríṣun àwòrán, @Albert

Àkọlé àwòrán,

Ojo arooroda fa omiyale, agbara ya soobu ni Ghana

O kere tan eniyan mejilelogun lo ti doloogbe ni orilẹ-ede Ghana bayii.

Lataari arọọrọda ojo to n rọ lati ọjọ mẹjọ sẹyin lo ti fa omiyale ati agbara ya ṣọọbu ni ariwa ila oorun Ghana.

Oríṣun àwòrán, @Albert

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ ile lo dawo ti opọlọpọ dukia si bajẹ ni Ghana

O le lẹgbẹrun kan ile to ti da wo silẹ ti ọpọ eeyan ko si nile lori mọ ni ẹkun yii

Ẹru n ba awọn alaṣẹ Ghana pe ki oku ma lọ pọ sii ju bayii lọ, ti awọn ti wọn ko nile lori naa si n pọ sii.

Oríṣun àwòrán, @Albert

Àkọlé àwòrán,

Opo ile ti ko duro daadaa tẹlẹ ni wọn ti wo lulẹ bayii ni Ghana

Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni Ghana, National Disaster Management Organisation ti berẹ si ni pin awọn ohun eelo fawọn ti omiyale le kuro nile.

George Ayisi to jẹ alukoro ajọ naa ṣalaye pe, oku eniyan mejilelogun ni wọn ti ri bayii ni eyi ti awọn ogoje eeyan dẹ ti di alainile lori.

Pupọ ninu awọn ti ile wọn ti wo ni wọn ti ko lọ sile ijọsin lawọn ṣọọṣi wọn ati awọn ile iwe kọọkan.

Àkọlé fídíò,

Omiyale Ile Ife: Dukia sọfọ, awọn eniyan si tun farapa

Ajọ to n woye ayipada oju ọjọ ni orilẹ-ede Ghana ti sọ pe ọpọ ojo lo ṣi maa rọ sii lọdun yii ni Ghana.

Osu kẹrin, ọdun yii niru omiyale bayii ṣẹle gbeyin ni Ghana.

Àkọlé fídíò,

È gbọ òun ti ojú awọn ara ipinle Ogun rí lọwọ ìṣẹlẹ omiyale

Àkọlé fídíò,

Painter: Samuel ni ìdàgbàsókè Nàìjíríà ló jẹ òun lógún!