JAMB: akẹ́kọ̀ọ́ tí kò bá ní nọ́mbà ìdánimọ NIN kò ní lè kọ ìdánwò ìgbaniwọlé

Awọn akẹkọ idanwo aṣewọle s'ile ẹkọ giga, JAMB Image copyright @JAMB
Àkọlé àwòrán Pupọ akẹkọọ Naijiria ni yoo kọ idanwo JAMB ki wọn to le ribi wọle si ile ẹkọ giga

Ajọ n to risi eto idanwo igbaniwọle si ile ẹkọ giga ni Naijiria, JAMB ti tẹpẹlẹ pataki nini nọmba idanimọ NIN fawọn akẹkọọ to fẹ kọ idanwo rẹ.

Ajọ naa ko ṣẹsẹ sọ ọrọ yi ṣugbọn o tun fi ikilọ yi sita loju opo Twitter rẹ pe akẹkọọ ti ko ba ni nọmba idanimọ NIN ko ni le kọ idanwo rẹ Láìsì nọ́mbà ìdánimọ̀ NIN ní 2020; kò sí ìdánwò- JAMB.

Yatọ si ikilọ yi o tun sọ fawọn akẹkọọ pe ki wọn ma ṣe san owo abẹtẹlẹ foṣiṣẹ JAMB kankan tori pe eleyi lodi sofin.

Ikilọ mejeeji yi wa loju opo Twitter wọn ni idahun si ibeere tawọn akẹkọọ kan fi ṣọwọ si oju opo naa.

Ọrọ yi ti wọn fi sita mu iriwisi ọtọọtọ wa.

Àkọlé àwòrán Ààrẹ Muhammadu mú àdínku ba owó ìdánwo fún ìr'srún òbí-JAMB

Bi awọn kan ti ṣe n gbosuba karẹ fun Jamb fun igbesẹ yi lawọn miran n bẹnu atẹ lu u pe ọna ati dagbese sawọn akẹkọọ ati obi wọn lọrun ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPainter: Samuel ni ìdàgbàsókè Nàìjíríà ló jẹ òun lógún!

Lẹnu ọjọmẹta yi ni ọrọ nọmba NIN ti n mu ikunsinu wa lati ọdọ awọn ọmọ Naijiria nitori inira ti wọn n koju lati ri gba ati bi ajọ NIMC ti ṣe sọ pe awọn eeyan yoo san owo lati fi gba kaadi idanimọ ti ti tẹlẹ ba sọnu.

Pupọ ọmọ Naijiria ni o ti forukọsilẹ ti ko ti ri kaadi idanimọ yi gba ti awọn miran ko tilẹ ti ribi forukọ silẹ.

Ijọba Naijiria ti ṣaaju kede pe nọmba NIN yi ni awọn yoo maa lo latifi ṣeto to ba ni ohun ṣe pẹlu iforukọsilẹ ni Naijiria yala fun iwe irinna, iwe aṣẹ iwakọ tabi nnkan miran.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTi o bá dá ara ẹ lójú, ki ẹni tó n ṣe irun kí n gbọ́?