Lady Gaga àti olólùfẹ́ rẹ̀ ṣubú yakata níbi tó tí ń kọrin ní Las Vegas

Lady Gaga Image copyright Getty Images

Ọna ọfun, ọna ọrun, olorin takasufe ilẹ Amẹrika, Lady gaga ṣubu yakata lori itage to ti n kọrin niluu Las Vegas.

Iṣẹlẹ yii waye nigba ti Lady Gaga fẹ pe ọkan lara awọn ololufẹ rẹ, Jack pe ko goke wa.

Bi Lady Gaga ṣe fo soke, to si bẹrẹ si nii jo ni ẹsẹ rẹ yẹ lori itage, lo ba ṣubu yakata.

Ẹnikan ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ ni ọpọ lo ro pe olorin naa ti ku lẹyin to ṣubu, amọ o jẹ iyalẹnu pe, o tun goke wa pẹlu Jack to fẹ fa soke pẹlu rẹ.

Egungun ṣubu, o sọ didan ni Lady Gaga fi ṣe, lẹyin to sọ pe awọn mejeeji fẹran ara wọn debi pe awọn jọ jabọ lati ori itage.

O ni ọrọ awọn dabi Jack ati Rose ninu fiimu Titanic. Ko da Lady Gaga ni o yẹ kawọn jọ muti papọ.

Ọpọ ololufẹ Lady Gaga lo bẹru fun Lady Gaga nitori o ni nnkan to maa n jẹ ki irora pọ sii lara eeyan ti wọn n pe ni 'Fibromyalgia'.

Lọdun 2013, Lady Gaga wọgile erongba rẹ lati lọ kọ orin 'Born This Way' lẹyin to fi itan rẹ ṣeṣe.

Ṣugbọn lẹyin iṣẹlẹ naa, Lady Gaga sọ fawọn ololufẹ rẹ pe kokoko lara oun le.