Lẹ́yìn ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n; àwọn èèyàn sí n bèèrè pé: Ta ló pa Dele Giwa?

Aworan Dele Giwa Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Lẹ́yìn ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n; àwọn èèyàn sí n bèèrè pé: Ta ló pa Dele Giwa?

Bi a ba ni ka maa p'ori akọni laarin awọn akọroyin orile-ede Naijiria, ko si igba ti ida Dele Giwa ko ni lalẹ gaaraga.

Olootu agba iwe iroyin Newswatch jẹ ọkan lara awọn oniroyin ti o dantọ ni Naijiria ki ọlọjọ to de.

Loni to pe ọdun mẹtalelọgbọn ti ọmọ Giwa dagbere faye, ọpọ eeyan lo ṣi n daro rẹ ti wọn si n beere ẹni to wa nidi iku rẹ.

Loju opo Twitter awọn eeyan bi Ahmed Salkida n ṣe idaro Dele Giwa.

Bẹẹ lọpọ n beere ibeere nla pe awọn oniṣẹ ibi wo lo ṣe iṣẹ naa.

Bawo ni Dele Giwa ṣe ku?

Ọrọ iku rẹ jẹ nnkan to ṣokunkun titi di bi a ti ṣe n sọrọ yi.

Orisirisi alaye si ni awọn eeyan ti fi sita lati na ika si awọn ti wọn lero pe o lọwọ ninu iku rẹ.

A ko ridi eyikeyi awọn alaye yi fi mulẹ ṣugbọn ohun ti ko ruju ni pe ado oloro ni wọn fi pa Dele Giwa eleyi ti wọn gbe sinu apo ifiweranṣẹ si ni.

Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ọrọ iku rẹ jẹ nnkan to ṣọkunkun titi di bi a ti ṣe n sọrọ yi.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC, Kayode Soyinka to jẹ olootu iwe iroyin Newswatch ni London sọ pe oun ati Dele Giwa jijọ wa nile rẹ ni GRA lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 1986 ni.

Ọjọ buruku, Eṣu gbomi mu naa bọ si ọjọ Aiku.

Iyawo Dele Giwa, Funmilayo gẹgẹ bi Kayode ti ṣe sọ gbe akara fun wọn ti wọn si jijọ n ṣaroye nipa bi awọn ọtẹlẹmuye ti ṣe fọrọ wa Dele Giwa lẹnuwo ṣaaju ọjọ naa.

Ṣaa deede ni wọn gbọ ti eeyan kan n kan ilẹkun ti ọmọ Dele Giwa, Kayode si wa jiṣe apo iwe naa fun Dele Giwa lọjọ naa.

Kete ti Dele Giwa ṣi apo iwe yii ni ado oloro bu gbamu ti o si gbina jẹ.

Ori ko Kayode Soyinka yọ ninu ibagbamu ado oloro naa amọ o farapa diẹ.

Toun ti pe wọn tara ṣaṣa gbe e lọ si ile iwosan, Kayode sọ pe ibẹ ni o dakẹ si.

Nigba ti iṣẹlẹ yi waye lọdun 1986, Naijiria si wa labẹ ijọba ologun labẹ akoso Ọgagun Ibrahim Babangida.

Igba akọkọ si re e ti wọn yoo fi ado oloro pa eeyan ni Naijiria.

Image copyright Yusuf Mohammed
Àkọlé àwòrán Dele Giwa, Yakubu Mohammed ati dokita Doyin Abiola

Iṣẹlẹ naa titi di oni jẹ eleyi ti awọn eeyan ṣi fi n ṣakawe ewu to wa nibi iṣẹ akọroyin ni Naijiria.

Awọn ọmọ Naijiria miran wo ni iku wọn mu ibeere dani?

Yatọ si Dele Giwa, awọn ilumọọka ọmọ Naijiria miran ti o kuku ojiji ti a ko le sọ awọn to pa wọn la ti ri awọn bii:

  • Kudirat Abiola
  • Bola Ige
  • Harry Marshall
  • Chuba Okadigbo
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAdebisi Olabode: Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti fòfin de oyè Ìyá àti Babalọja