Kano Zoo: Àfihàn ohun ọ̀gbìn ló mú kí wọ́n mú Kìnìún náà jáde

Àkọlé àwòrán Kano Zoo: Kìnìún sá kúrò ní ọgbá ẹrànko lẹ́yìn to ṣe ọsẹ́ nínú ọgbà ẹranko

Iroyin to n tẹ́ wa lọ́wọ́ fi ye ni pe wọn ti ri kiniun to sa lọ lgba ẹranko nilu Kano bayii.

BBC gbọ pe inu agọ ti wọn fi awọn ewurẹ pamọ si ni wọn ti ri Kiniun naa, to si ti pa gbogbo ewurẹ to wa nibẹ patapata.

Laipẹ yii la mu iroyin naa wa fun yin ni yajoyajo pe inu ibẹ̀rù bojo làwọn olùgbé àdúgbò òpópónà Zoo ní ìpínlẹ̀ Kano wa, nìgbà ti kìnìún kan sá kúrò nínú ọgbà ẹrànko to wà ní Kano, lóru ọjọ́ Sátidé.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ìròyìn to tẹ BBC lọ́wọ́ sọpé, ìsẹ̀lẹ̀ náà wáye nígbà ti kìnìun ọhun fipa jáde lásìkò ti olùsọ wọ́n ń gbiyanju láti dáá pada si ààye rẹ̀, lẹ̀yin ti wọ́n se ayẹyẹ àfihan ohun ọ̀gbìn.

Adari ibudo ẹranko nilu Kano, Saidu Gwadabe Gwarzo sàlàye pé, wọ́n ba Kìnìún ọhun ni ìhà ibi ti àwọn ewúrẹ wà, ti Kìnìun náà si ti ń pa àwọn ewúrẹ́ jẹ.

Image copyright Others

Gwadabe fi kún-un pé, ni ọjọ sátide ni wọ́n tun sílẹ̀ ni abala tawọn ẹranko ẹgan wa ninu ọgba ẹranko naa ni Kano, amọ to salọ nigba ti wọn fẹ pada si ibudo rẹ̀.

Agbẹnusọ ọlọpàá ní ìpínlẹ̀ Kano, DSP Abdullahi Kiyawa, ti wa fi ìdì ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀.

Àkọlé àwòrán Oṣeṣe ki ẹ dede pàde kìnìún lọ́na

Olùdari ọgba ẹranko naa sọ pe Kìnìún náà wa ninu ọgbà, àti pé gbogbo ẹnu ibode to wọ ibudó náà ni àwọn ti ti pa.

Àwọn alaṣẹ ti wa kesi gbogbo olùgbé ìpínlẹ̀ Kano, pàápàá jùlọ àwọn to wa ni agbegbe ọgba ẹranko naa, láti fi ọkàn wọn balẹ̀, nítori pé àwọn yóò sa gbogbo ipá àwọn láti dààbo bò wọ́n.