Health Talk: Onímọ̀ ìṣègùn ní àìsàn tó o ṣe l‘óru yóò tètè sàn ju èyí tó o ṣe lọ́sàn-án lọ

Arun ti ko gboogun, Oluwa ma fi kan ni lawọn eeyan maa n gbaa ni adura.

Eyi fi han pe awọn aisan kan wa ti yoo se eeyan, ti yoo si gbọ wiwo, sugbọn o wa yẹ ka ni imọ nipa awọn akoko ta lee se aisan ti yoo gbọ oogun .

Gẹgẹ bi iwadi ninu fidio yii ti sọ fun wa, awọn akoko kan wa ti aisan ba se wa, akoko ti a ba se aisan naa ati akoko ta ba gba itọju fun iwosan, ni yoo sọ bi aisan naa yoo se tete san si.

A gbọ pe bi a ba se safihan agọ ara wa labẹ okunkun ati imọlẹ yoo sọ bi aisan naa yoo se tete san si.

Bakan naa, bi oju ọjọ ba se ri ni yoo sọ bi oogun taa lo yoo se sisẹ si, nitori iwadi ni oogun ta ba lo loru yoo sisẹ pupọ ju eyi taa ba lo lọsan gangan lọ, lasiko tawọn agọ ara wa n sisẹ lọwọ.

Ẹ wo fidio yii lati mọ ẹkunrẹrẹ alaye nipa bi a se lee tete ri iwosan lasiko ti agọ ara wa ba dasẹ silẹ.