Yemi Osinbajo: Seyi Makinde, mo gbà fún ọ lórí ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tó o ṣe l‘Ọyọ

Seyi Makinde n fun akẹkọ ni iwe ajakọ Image copyright @oyostategovt

Igbakeji aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo ti se sadankata, mo gba fun ọ, si gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde lori ilana ẹkọ ọfẹ to gbe kalẹ nipinlẹ Ọyọ.

Atẹjade kan ti akọwe gomina ipinlẹ Ọyọ feto iroyin, Taiwo Adisa fisita salaye pe, igbakeji aarẹ gbosuba bẹẹ fun Seyi Makinde lasiko ti wọn jọ peju sibi isin ayẹyẹ ọgbọn ọdun ti wọn da ijọ Bishop Taiwo Adelakun, Victory Church silẹ nilu Ibadan.

Osinbajo salaye inu oun dun pe gomina Makinde tẹwọgba ipenija to wa nidi ipese ẹkọ ọfẹ to tun jẹ ojulowo nipinlẹ Ọyọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Osinbajo fikun pe ijọba Muhammadu Buhari gan sọ logunjọ osu Kẹfa ọdun 2019 pe eto ẹkọ yoo jẹ ọfẹ yika orilẹede Naijiria fun ọdun mẹsan akọkọ nile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama, tijsba apapọ ko si lee kan nipa fawọn ijọba ipinlẹ lati se bẹẹ.

Image copyright @OfficialSeyiMakinde

O wa jẹjẹ pe ijọba apapọ yoo sisẹ pọ pẹlu awọn ipinlẹ lati se amusẹ ipese ojulowo ẹkọ ọfẹ pẹlu afikun pe ijsba yoo ran wọn lọwọ ni gbogbo ọna lati ri daju pe afojusun ipese ẹkọ ọfẹ, to tun jẹ dandan di ohun.

Nigba to n fesi, gomina Seyi Makinde ni ẹkọ ọfẹ ti di ohun nipinlẹ Ọyọ nitori ilana eto ẹkọ nikan ni ọna to daju lati mu adinku ba isẹ ati osi ati ilana ironilagbara to pegede julọ fawọn ọdọ.

"Lootọ ọdun mẹrin ko to lati gbe wa de ibi ti a n ls amọ ọdun mẹrin to lati fi ipilẹ gidi lelẹ fun eto ẹkọ, eyi ti ijsba to n bs yoo mọ le lori."

"Ọpọ awọn asaaju wa lo si n royin anfaani ẹkọ ọfẹ Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ ti wọn jẹ anfaani rẹ bi o tilẹ jẹ pe ọjọ pẹ ti Awolọwọ ti papoda. Sugbọn ipa ẹkọ ọfẹ ti Awolọwọ fi silẹ lo jẹ opo tijsba mi fẹyinti nipinlẹ Ọyọ."