USSD: Ìjọba àpapọ̀ bẹ̀rẹ̀ ìwàdíí lórí owó orí tí MTN fẹ́ yọ̀

Ẹrọ ibaraẹnisọrọ Image copyright Others

Mínísítà fùn eto ìbárẹnisọ̀rọ̀ Isa Pantami, tí pàsẹ oní wàrànsesà fún ilé iṣẹ́ MTN àti àwọn ilé iṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ míràn láti dẹ́kun ìpinu rẹ̀, lóri fífi náírà mẹ́rin owó àtẹjisẹ lorí onibara rẹ̀, tó fẹ fi owo rànsẹ́ sí ẹlòmíràn láti orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀.

Èyí jẹ́ ìdáhun sí igbé àwọn ọmọ Nàìjíríà lori àba ti ilé iṣẹ́ MTN dá pé, yóò bẹ̀rẹ̀ si ni yọ ààdọta naira láti ọjọ kọkanlélogun osù yìí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ̀ " wọ́n ti pe àkíyèsí ilé iṣẹ́ to n se akoso eto ìbáraẹnisọ̀rọ̀ Nàìjíríà, sí ìpínu ilé iṣẹ́ MTN láti máa yọ nàira mẹ́rin láàrin ogún ìṣẹ́jú ààyá bí owo àtẹjisẹ́ si bánkì."

Atẹjade kan ti ileesẹ to wa fọrọ ibaraẹnisọ̀rọ lorilẹede yii lo kede bẹẹ nilu Abuja .

Atẹjade naa ni "Mínísítà fún ìbáraẹnisọ̀rọ̀, ọmọwé Isa Ali Ibrahim Pantami kò mọ̀ nípa ìgbésẹ̀ yìí, ó sì ti pàsẹ fún àwọn to n moju to ijagaara eto ibanisọrọ ni Naijiria (NCC), láti ríi dáju pé ilé iṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ MTN ṣẹ́wélé ìpinu rẹ̀, títí ti wọ́n yóò fi wá wi tẹnu wọn fún Minisità"

Àkọlé àwòrán USSD: A ti pàssẹ fún ilké iṣẹ́ MTN láti ma gùnlé ìpinnu wọ̀n

USSD Tax: Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà ń fapá jánú pé owó orí ti pọ̀ jù

Image copyright Others

Ọrọ owo ori gbigba ti gba ọna miran yọ bayii nitori owo ori tun ti gun igbesẹ fifi owo ransẹ lati ori ẹrọ ibaraẹnisọrọ.

Se ni awọn ọmọ Naijiria bẹrẹ si ni gba atẹjisẹ kan lati ileesẹ ibaraẹnisọrọ Kan, MTN lọjọ Satide pe, nibamu pẹlu adehun ti ileesẹ ibaraẹnisọrọ naa ati awọn banki ilẹ wa, oun yoo maa yọ owo ori lori awọn owo ti onibara kọọkan ba fi ransẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ọmọ Naijiria naa tun salaye pe owo ori tawọn n san ti pọ ju, ti ko si si ẹni to mọ ohun ti wọn n fi se.

Image copyright Others

@EVheeky loju opo rẹ n beere pe ki lo de ti banki oun, Zenith fi ni ki ileesẹ ibaraẹnisọrọ MTN maa tun gba owo lọwọ oun, se oun lo fi wọn han ara wọn ni?

@Oluwaroll1 naa n beere pe se ileesẹ́ MTN ati banki oun , GTB ti pawọpọ ni lati ba owo jẹ mọ awọn eeyan lọwọ? Koda, ohun ti owo ori yii wa ko tii ye oun.

@JasmineEsset naa n gbarata pe se a tun maa sanwo ori fun lilo ẹrọ ibaraẹnisọrọ lati fi owo ransẹ ni? Ki wa ni orilẹede Naijiria n da bayii?

@DoctorEmto, oun tiẹ sọ yanya pe banki Zenith ti n yọ naira mẹẹdogun bii owo ori ti oun ba fi owo ransẹ lati ori ẹrọ ibaraẹnisọrọ.

@tejumania tiẹ́ n pariwo ni pe ki loun se ti Ọ́lọrun fi da oun si orilẹede Naijiria? Awọn owo ori ti wọn n gba lọwọ ara ilu ti n pọ ju lai si ohunkohun ti wọn n fi se.