Davido: Àpètàn orukọ̀ ọmọ tuntun náà ní David Adedeji Ifeanyi Adeleke

David Adeleke taa mọ̀ si Davido Image copyright @davidoofficial

Ayọ abara tintin. David Adeleke, ti gbogbo eeyan mọ si Davido ti kede pe, Oluwa ti fi ọmọkunrin kan lanti-lanti da oun ati aya oun, Chioma, lọla.

Owurọ ọjọ Aiku ni Davido kede bẹẹ loju opo Instagram rẹ, to si ni Ọmọọba ti de, ile iwosan kan nilu London si ni Chioma bimọ naa si.

O wa pe orukọ ọmọ ọhun ni David Adedeji Ifeanyi Adeleke Jnr pẹlu afikun pe inu oun dun pupọ si iroyin ayọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Davido ni "Mo nifẹ aya mi pupọ, koda obinrin alagbara ni", to si jẹ pe nigba ti awọn olorin to jẹ akẹẹgbẹ Davido n lọ sibi ami ẹyẹ fawọn olorin, Headies Award, yara igbẹbi ni Davido wa, to n rawọ rasẹ si Ọlọrun pe, ko sọ aya oun kalẹ layọ.

Image copyright @davidoofficial

Chioma, afẹsọna Davido lo ti kọkọ kede loju opo Twitter rẹ nirọlẹ ana pe oun wa nile igbẹbi, ti ọpọ eeyan si ti n se adura fun pe yoo bi wẹrẹ.

Koda, oun naa tun ti kede loju opo Instagram rẹ pe Oluwa ti sọ oun layọ.

Wayi o, awọn ọmọ Naijiria ti n se jaginni yodo pẹlu ọba orin naa fun ayọ ọmọkunrin jojolo to baa lalejo naa, bi o tilẹ jẹ pe obinrin meji ọtọọtọ ti bi ọmọbinrin meji fun tẹlẹ.