Army: Ọkọ mẹ́sàn-án tó kún fún àpò ẹja la gbà lọ́wọ́ Boko Haram

Apo ẹ́ja gbigbẹ́ ti awọ̀n ologun n dana sun Image copyright @HQNigerianArmy

Ọgbọn kii tan laye, ka wa lọ sọrun ni awọn Boko Haram n fi iwalaaye wọn se, ti wọn si n da ọgbọn orisirisi lati mu ki igbe aye idẹrun wa fun wọn.

Gẹgẹ bi ileesẹ ologun ilẹ wa ti kede bayii, se ni awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram n da ọgbọn lati maa se okoowo ẹja gbigbẹ, eyi ti wọn n ko wọle lati awọn orilẹede to mule ti orilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade kan ti ileesẹ ologun fisita ni ọwọ tẹ ọkan lara awọn adunkooko mọni yii , ẹni to jẹ pe isẹ to yan laayo n tiẹ ni lati maa gbe ẹja gbigbẹ wa sorilẹede yii lati orilẹede Lake Chad to mule ti wa.

Image copyright @HQNigerianArmy

Ọgagun Aminu Illyasu, tii se agbẹnusọ fun ileesẹ ologun ilẹ wa, ninu atẹjade naa ni iwadi ti fihan pe owo ti awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram ọhun ba ri nidi katakara ẹja gbigbẹ ni wọn n lo lati fi gbọ bukata ara wọn ati isẹ ibi ti wọn n se.

Image copyright @HQNigerianArmy

"Ere ti wọn ri nidi tita ẹja gbigbẹ ti wọn n ko wọle ni wsn n lo lati fi ra eroja ounjẹ, eso, oogun ti wọn n lo, awọn ohun eelo ojoojumọ ninu ile, ẹya ara ọkọ ati awọn ohun eelo miran to wulo fun isẹ apaniyan ti wọn rawọ le."

Ọgagun Illiyasu fikun pe lasiko ti awọn ologun n paraaro agbegbe Bukarti, nijọba ibilẹ Geidam nipinlẹ Yobe, ni ọwọ wọn tẹ ọkọ mẹsan kan to kun fun ẹja gbigbẹ, ti wọn si mu afurasi mejidinlogun si ahamọ, to fi mọ awakọ awọn Boko haram naa, agbero ọkọ, atọkọse wọn ati awsn asoju wọn lorisirisi ọna.

Image copyright @HQNigerianArmy

Idà ahun pa ahun! Àdó ikú tí Boko Haram fi sójú ọ̀nà pa méje lára wọn

Ikọ ọmọogun Naijiria ti kede pe ikọ Boko Haram ti fun ra wọn ko si idẹkun ti wọn dẹ silẹ fun ikọ ọmọogun Lafia Dole.

Ninu atẹjade kan ti Adari Iroyin fun ikọ ọmọogun Naijiria, Ọgagun Aminu Iliyasu fi lede ni, awọn agbesunmọmi Boko Haram meje lo ku ninu ado oloro to bu gbamu naa, leti ẹba ọna ti wọn fi dẹkun si, ti mẹjọ si farapa.

Ikọ ọmọogun Naijiria ni, awọn ti wọn sagbako ado iku naa n sa asala fun ẹmi wọn, lẹyin ti ikọ Lafia Dole da ina bo wọn ni agbeegbe Jakana-Mainok ni ipinlẹ Borno, ti wọn sa pamọ si.

Image copyright @HQNigerianArmy
Àkọlé àwòrán Boko Haram méje faragbá àdó olóró tí wọ́n fi sí ẹ̀bá ọ̀nà!

Ọkọ ayokẹle Toyota ti ikọ Boko Haram naa n lo lati sa kuro lagbeegbe naa lo gbina, lẹyin ti wọn gun ori ado oloro ti wọn fi dẹkun silẹ.

Bakan naa ni Ikọ ọmọogun Naijiria fikun wi pe, gbogbo eto ti to lati ri wi pe ko si ikọ Boko Haram mọ ni agbegbe naa.