N kò fẹ́ ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó ló mú mi máa wa ọkọ̀ taxi - Obìnrin tó ń wa Uber
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Taxi Lady: Bùkátà pọ̀ lọ́rùn mi ní mo ṣe ń wa taxi akérò

Ohun ti ọkunrin lee se, obinrin miran lee se daradara ju ọkunrin lọ, idi si ree ti obinrin kan Princess Igbafe fi yan isẹ awakọ ero taxi laayo.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Princess ni ohun ko to ọmọ ọdun mejidinlogun, ti oun ti n da gbe pẹlu aburo oun ọkunrin, ti ọpọ bukata si wa niwaju oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Princess salaye pe oun maa bọ ẹnu oun ati ti aburo oun, pẹlu sisan owo ile ati ileewe aburo oun, lo mu ki oun gba idi wiwa ọkọ akero lọ.

O wa gba awọn obinrin nimọran pe ọpọ isẹ wa nilẹ ti wọn lee se lai se owo nabi, yoo si dara ki wọn wa isẹ aje se dipo tita ara wọn fun ọkunrin.