Ilé ẹjọ́ ní pásítọ̀ yóò fi ẹ̀wọ̀n jura bí kò bá gbé ṣọ́ọ̀ṣì aláriwo rẹ̀ kúrò ládúgbò

Ile ijọsin kan Image copyright Getty Images

Ile ẹjọ Majisireeti kan ni ilu Nnewi ti paṣẹ ki wọn ti ile ijọsin igbalode kan pa nitori ariwo.

Ileeṣẹ ilera ayika ati ijsba ibilẹ Ariwa Nnewi, Nnewi North lo pe awọn adari ileejọsin naa lẹjọ ti wọn si fun wọn ni ọjọ mẹwa lati fi gbe ile ijọsin wọn kuro.

Ẹsun ti wọn fi kan ile ijọsin naa ni pe o gbe awọn ẹrọ gboungboun ati amohundungbẹmu si iwaju ile ijssin rẹ eleyii ti wọn ni o yi soke la-la-la lati fi da araalu laamu lọsan ati loru.

Awọn olupẹljọ ni ohun ti ijọ naa n ṣe lewu fun ilera ọmọniyan, o si tako ofin ilera ipinlẹ Anambra tọdun 2006.

Ninu idajs to gbe kalẹ, Adajọ Emekwe AC paṣẹ fun ileeṣẹ ilera ayika ati ijọba ibilẹ nnwi North lati ls ti ile ẹjs naa pa ki wọn si so ileejọin naa lọwọkọ lori ṣiṣe iṣẹ isin nibẹ.

Bakan naa ni il ẹjs paṣẹ pe bi ileejọsin naa ko ba gbe ile ijọsin rẹ kuro laarin ọjọ mẹwaa, yoo fi ẹwọn ọdun kan jora

Related Topics