Kèǹgbè lílù ní Ilọrin rèé, orin ìgbéyàwó, àwàdà àti ẹ̀ẹ̀kẹ́ èébú
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kengbe Ilorin: Àṣà ẹ̀yà Fulani, Bariba àti Gambari tó dàpọ̀ mọ́ ti Yoruba

Orisirisi orin ati ilu ni ẹya Yoruba fi maa n da ara wọn laraya laye atijọ bii Bọlọjọ, Sakara, Sẹnwẹlẹ, Apala, Were, Waka, Kengbe lilu ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Sugbọn asa Kengbe lilu yii lo wọpọ nilu Ilọrin lasiko igbeyawo, idaraya fun ọba ati nibi orisirisi ayẹyẹ miran.

O wa se ni laanu pe lode oni, asa Kengbe lilu naa ti n lọ sokun igbagbe, ti ọpọ eeyan ko si ya sidi rẹ mọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ ọkan lara awọn to jogun ba asa Kengbe lilu naa, Ramat Olowo sọ fun BBC Yoruba pe, oun ti pinnu lati tun se agbende asa naa pada ko ma parun.

Ramat ni orin to wa ninu Kengbe lilu maa n danilaraya, kọ ni lọgbọn, to si tun maa n pa ni lẹrin, paapa awọn orin aro, awada, idọwẹkẹ, amusẹya ati ẹẹkẹ eebu to kun inu rẹ.

Ramat Olowo fikun pe ẹya Ibariba, Fulani ati Gambari lo ko asa lilu Kengbe wa si Ilọrin amọ o ti yi wọnu asa Yoruba, ti ko si yẹ ko parun.

Ẹ wo fidio yii lati mọ bi orin naa se dun to.