Seyi Makinde: Pálí Ìṣáná la fi ń bẹ ẹlòmìí l'Oyo kí wọ́n tó ṣe ètò ìlera ọ̀fẹ́ - Kọmíṣánà

Gomina Makinde ati iyalọmọ kan nile iwosan Jericho niluu Ibadan Image copyright @seyiamakinde

Kọmiṣana fun eto ilera ni ipinlẹ Oyo labẹ ijọba gomina Seyi Makinde, Bashir Bello jẹ ko di mimọ pe kii ṣe pe ile iṣẹ to n ri si eto ilera ko ni eto iranwọ nilẹ.

Bashir ni arabinrin yii kan ṣaa ṣe kongẹ alaanu ninu gomina Seyi Makinde ni tori kii ṣe gbogbo eniyan lo lee duro gbọ iru ọrọ bẹẹ.

Lọjọ aje ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde nawọ aanu si abiyamọ yii atawọn alaisan mẹta miiran ti wọn ni ipenija owo lati tọju ara wọn nile iwosan to wa ni Jericho nilu Ibadan.

Gomina Makinde se alabapade awọn alaisan naa lasiko to lọ se abẹwo sile iwosan naa lati mọ ibi ti isẹ de duro nibẹ.

A gbọ pe obinrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Tolulọpẹ Thompson lo sadede lọ sa ba gomina Makinde ni kete to foju kan-an nile iwosan ọhun, lasiko ti gomina n jade sita.

Nigba ti BBC Yoruba beere pe ṣe ile iṣẹ to n ri si eto ilera ko ni eto kankan to n ran araalu lọwọ ni, Kọmiṣana ni,

"Ẹ ṣaa mọ bi awọn eeyan wa ṣe ri, bẹẹ ba fẹ sọ fun awọn eeyan alawọdudu pe ki wọn wa soriire, ẹẹ tun fẹẹ ṣe aajo si i".

Kọmiṣana ṣalaye pe oniruuru ni eto ti ijọba gomina Seyi Makinde ti gbe kalẹ lati ran eto ilera awọn araalu lọwọ.

Eto ilera alabọde, eto adojutofo ati ọpọlọpọ mii ṣugbọn iha ti ọpọ araalu n kọ si awn eto yii ni ko ba a mu.

"Arabinrin naa ko ṣeto ilera ti ijọba tori ọpọ awọn ti wọn ba ni ki wọn wa seto ilera alabọde yii ko ni imọ kikun nipa rẹ; bi wọn ba tilẹ ni imọ kikun, wọn o ki n ya si i".

Kọmiṣana ni "afi ki ẹ tun maa fi tori Ọlọrun bẹ awọn araalu mii".

O ṣalaye pe awọn iyalọmọ mii gan ko ki n lọ gba abẹrẹ to yẹ ki wọ́n gba fun ọmọ wọn pe afi igba ti wahala ba kan ilẹkun ni ede to maa n ye ẹlomiran.

O ni gbogbo eto lo ti wa nilẹ lati mu nkan dẹrun ṣugbọn lasiko to ba rọ wọn lọrun ni wọn maa n fẹ ṣe nkan.

Ni ti arabinrin Tolulope atawọn mii to ri owo iranwọ́ ẹgbẹrun lọna aadọta naira gba, o ni wọn kan ṣe kongẹ ire ni tori iru eniyan ti gomina Seyi makinde jẹ lawujọ.

Ẹwẹ, o ni eto ilanilọyẹ fun ilera ni o tun yẹ ki awọn fi kun ohun tawọn ti n ṣe latẹyin wa ki awọn eeyan le mọ pe eto ilera ọfẹ ti wọn n pese, fun anfani wọn ni.

Kọmiṣana fi iha ti awọn eeyan n kọ si eto ilera ọfẹ laye ode oni we bii ọgọrin ọdun o le sẹyin lasiko ti oun wa ni kekere ti wọn maa n sare si i. Eyi lo jẹ ko sọ wi pe ọ̀tọ ni keeyan laju si iru eto iranwọ ijọba bayii, ọtọ si ni kiru ẹni bẹẹ ni laakaye kikun nipa rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Thompson lo kigbe si gomina, to si n rọ pe ko ba oun san owo ile iwosan ti wọn kọ fun eto ayẹwo ara ọmọ oun (scan), ki awọn dokita lee mọ oun to n se e.

Image copyright @OEOlatunde

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, amugbalẹgbẹ fun gomina ipinlẹ Ọyọ feto iroyin, Taiwo Adisa salaye pe lootọ ni gomina Makinde fun obinrin kan to tọ gomina wa pe ọmọ ẹyin oun ti fẹ ku, ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira.

Adisa ni ọmọ to wa lẹyin obinrin naa lo ti rọ wọjọ sẹyin rẹ, ti ẹnikẹni ko si mọ boya ọmọ naa ti daku, ti awọn ẹsọ gomina si n le obinrin naa sẹyin, amọ ti gomina ni ki wọn fi silẹ, ki awọn gbọ ohun to fẹ sọ.

O ni sadede ni obinrin ọhun kunlẹ wọ, to si n rawọ-rasẹ si gomina Makinde pe ko gba oun kalẹ, ki ọmọ oun ma baa ku, nitori agbara ko si fun lati sanwo fun ayẹwo naa tile iwosan ni ki oun lọ se.

Image copyright @OfficialSeyiMakinde

Amugbalẹgbẹ gomina feto iroyin fikun pe lọgan ni gomina Makinde tẹwọgba iwe ile iwosan to mu lọwọ, to si fun aya Thompson ni ẹgbẹrun lsna aadọta naira, eyi to ju iye owo to beere lọ.

"Ko pẹ ti gomina se eyi tan, to fẹ wọ yara ayẹwo laboratory ni awọn alaisan mẹta miran tun yọju siwaju gomina, tawọn naa si n beere pe ko ran awọn lọwọ lati san owo iwosan awọn."

"Eyi lo mu ki gomina Makinde pasẹ pe ki wọn tun fun ikọọkan awọn alaisan mẹtẹẹta yii ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira, gẹgẹ bo se fun Tolulọpẹ Thompson saaju."

Image copyright @OfficialSeyiMakinde

Ìjọba Ajimọbi kúndùn níná owó gọbọi lórí iṣẹ́ àgbàṣe tó ń ṣe ní àṣepatì - Seyi Makinde

Bakan naa, gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde tun ti fọwọ mejeeji sọya fun awọn olugbe ipinlẹ Ọyọ pe, oun ko ni na owo wọn ni inakuna, gbogbo ohun ti ohun ba fi owo wọn se, ni wsn yoo fi oju ri.

Gomina Makinde jẹjẹ yii lọjọ Aje lasiko to n se ayẹwo awọn isẹ agbase mẹta nilu Ibadan, tii se olu ilu ipinlẹ Ọyọ.

Gomina Makinde lo sabẹwo gareji ọkọ to wa ni Sango, ile iwosan Jericho ati ile igbẹbi tuntun to wa ladugbo Jericho bakan naa, to si koro oju si ipo tawọn dukia ijọba ọhun wa, paapa awọn ilẹ ati ọpọ ohun eelo ti wọn ti pa ti.

Gomina ni asa ti ko dara ni ki wọn maa na owo ilu ninakuna lori awọn isẹ agbase kan, ki wọn si pada wa pa isẹ ọhun ti nigba ti isẹ naa ba de idaji, lai naani owo tuulu ti wọn ti na le lori.

Gomina Seyi Makinde n wo alaisan lori ibusun

Image copyright @OfficialSeyiMakinde

Makinde ni iru asa yii lo wọpọ lasiko ijọba to kogba wọle nipinlẹ Ọyọ, to si tun seleri fawọn eeyan ipinlẹ naa pe ijọba oun yoo ri daju pe wọn fi oju ara wọn ri ohun ti oun ba fi owo ilu se.

Makinde wa pasẹ fun oludari ileesẹ to n sakoso eto irinna loju popo nipinlẹ Ọyọ, Ọmọwe Akin Fagbemi, lati gbe olu ileesẹ rẹ lọ si gareji ọkọ atijọ to wa ni Sango, pẹlu ileri pe oun yoo pese awọn ohun elo to yẹ sibẹ feto idẹrun isẹ wọn.

Bakan naa ni gomina Makinde tun seleri nile iwosan mejeeji to wa ni Jericho lati pese awọn ohun eelo iwosan igbalode sawọn ibudo mejeeji naa fun agbelarugẹ eto ilera to peye.