Botswana: Ìdí tí erin àti òkúta Dáyámọ́ǹdì yóò fi leè sọ olúborí èsì ètò ìdìbò ààrẹ

erin Image copyright Getty Images

Orilẹede Botswana yoo ṣeto idibo apapọ rẹ lọjọ kẹtalelogun oṣu kẹwa, bẹẹni eto ifọrọwerọ ti BBC World Questions debate gbe kalẹ ti ṣe awari rẹ ni ilu Garborone pe ipa diẹ kọ ni okuta iyebiye Dayamọndi ati erin lee ko ninu esi idibo naa.

Ẹgbẹ oṣelu Botswana Democratic Party, (BDP) lo ti n bori gbogbo idibo to n waye lorilẹede Botswana lati igba ti wọn ti gba ominira lọdun 1966, amọṣa lọdun yii, o ṣeeṣe ki ọrọ ba ibomiran yọ fun wọn.

Mẹta ninu awọn ẹgbẹ alatako lo ti ko ara wọn jọ labẹ aburada ẹgbẹ Umbrella for Democratic Change (UDC)

Eto ipolongo ti wọn gbe kalẹ ni ileri ipese ẹgbẹrun lọna ọgọrun iṣẹ lorilẹede naa bi wọn ba wọle. Ni orilẹede to jẹ pe bii ida ogun ninu ọgọrun awọn eeyan rẹ ni ko ni iṣẹ lọwọ ti ọpọ to n ri iṣẹ ṣe gan ko lee fi ẹdọ lori oronro, ileri yii jẹ eyi to fa oju ọpọlọpọ oludibo mọra.

Image copyright Getty Images

Igbakeji Aarẹ ẹgbẹ oṣelu UDC, Dumelang Saleshando ṣalaye fun BBC debate pe 'o da lori eto ọrọ aje eyi to yọ ọwọ awọn araalu sẹyin.'

"Bi ẹ ba lọ si ẹka iṣẹ akanṣe, awọn ọmọ orilẹede China lo gba ibẹ. Bi ẹ ba lọ si ẹka karakata, awọn ọmọ ilẹ Aṣia lo n jaye ọba nibẹ...ko si ẹka ọrọ aje kankan lorilẹede yii ti awọn ọmọ orilẹede Botswana ti n moke."

Orilẹede ti a kọ sori okuta iyebiye Dayamọndi

Orilẹede Botswana ni ọpọ maa n pe ni itan aṣeyọri ilẹ Afirika - o gba ominira rẹ lai ta ẹjẹ silẹ gẹgẹ bi ọpọ awọn orilẹede to mule tii ṣe ṣe, ko fi igba kan ri ni wahala ogun abẹle bẹẹni eto idibo rẹ kii ni rogbodiyan ninu rara.

Pupọ ọrọ orilẹede Botswana lo da lori okuta iyebiye Dayamọndi. Bi o tilẹ jẹ pe orilẹede Russia n pese okuta iyebiye yii ju Botswana lọ, sibẹ ibudo iwakusa mẹrin lorilẹede Botswana lo n pese okuta iyebiye Dayamọndi to dara julọ lagbaye.

Biliọnu mẹta abọ dọla owo ilẹ Amẹrika, $3.5bn ni okuta iyebiye yii ko wọ apo ijọba orilẹede naa lọdun to kọja nikan. Eyi si ja si ida ogoji ninu ọgọrun eto ọrọ aje ilẹ naa.

Owo yii ti kọ opopona, ileewe ati ileewosan ṣugbọn lẹyin aadọta ọdun, ọpọ eeyan lo n woye pe owo to yẹ ki o maa wọle yẹ ko pọ ju eyi lọ.

Ni ọdun yii, iroyin iwa ijẹkujẹ gba ode kan lori ajọṣepọ to wa laarin ijọba orilẹede naa ati De Beers, ileeṣe kan to n wa kusa okuta Dayamọndi lagbaye.

Minisita fun ibaraẹnisọrọ ati irinajo, Dorcas Makgato ṣalaye lori iha ti ijọba orilẹede naa kọ si ijiroro idunadura pẹlu ileeṣẹ De beers.

Image copyright Getty Images

Amọṣa, Ọgbẹni Saleshando ko gba eyi gbọ. O ni ida marundinlọgọrun ninu ọgọrun awọn eeyan orilẹede naa ni ko fi oju wọn ri okuta dayamọndi ri. O ni otitọ ibẹ ni pe nṣe ni okuta iyebiye Dayamọndi naa n pese iṣẹ fun awọn orilẹede okeere ti awọn eeyan orilẹede naa kan joye awakusa lasan.

Pataki erin ninu ọrọ gbogbo

Orilẹede Botswana ni yoo fẹẹ jẹ orilẹede kan ṣoṣo lagbaye ti ọrọ erin yoo lagbara lori eto idibo.

Bi o tilẹ jẹ pe iye awọn eeyan rẹ ko pọ, iye erin to wa lorilẹede Botswana lo pọ julọ nilẹ Afirika. Eyi si n fa wahala laarin eeyan atawọn ẹranko lojojujmọ nibẹ. Labẹ aarẹ ana, Ian Khama, gba oriyin fun eto idaabo bo awọn ẹranko fun orilẹede Botswana.

Image copyright Getty Images

Kaakiri gbogbo agbaye ni wọn ti n gboriyin fun ijọba rẹ fun igbesẹ rẹ lati gbogun ti pipa awọn ẹranko lọna ti ko ba ofin mu.

Aarẹ Mokgweetsi Masisi ko dabi ẹni to fara si ohun ti awujọ agbaje sọ nipa aṣiwaju rẹ.

O woye pe bi o ba wu awọn ilẹ Gẹẹsi, ki wọn gbiyanju ati maa ba awọn erin orilẹede Botswana gbe bi wọn ba ni ifẹ wọn bẹẹ.

Image copyright Getty Images

Nibayii, aarẹ Mokgweetsi Masisi ti gbe ofin to de pipa erin lọna ti ko tọ kuro eyi si wa da oniruuru awuyewuye silẹ. Amọṣa o dabi ẹni pe igbesẹ yii dun mọ ọpọlọpọ awọn araalu ninu nitori nigba ti BBC beere lọwọ awọn eeyan nigboro, wọn ni awọn faramọ ọ.