Kogi Fraca: Àwọn ẹni àìrí kan ló já iná ilé mi ní ilé Ijọba.

Ija laarin Gomina ati Igbakeji re Image copyright @Achuba
Àkọlé àwòrán Igbakeji Gomina Ipinle Kogi

Ẹkọ ko ṣoju mimu fun ẹni ti o jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Kogi, Simon Achuba nigba ti wọn gba awọn ọlọọpa kuro lẹyin rẹ.

Achuba ni o ti ni ede aiyede pẹlu gomina ipinlẹ naa lati bii oṣu meji sẹyin ki awọn aṣofin Ile Igbimọ Ipinlẹ naa to yọ bii ẹni yọ jiga.

Ninu ọrọ rẹ, Achuba ṣalaye pe gbogbo ọlọpaa to yẹ ki o maa ṣọ oun ni wọn ti gba kuro lẹyin rẹ ti wọn si ju u si korofo.

Achuba wi pe, lẹyin eyi ni wọn tun yọ waya ti o gbe ina wọle si ile oun ti wọn si sọ gbogbo ile si okunkun.

O tẹsiwaju ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ pe, lẹyin ti wọn ja ina naa tan, ni oun tun tẹsiwaju lati tan ẹrọ amuna wa.

Ṣugbọn awọn kan bii Ọlọpaa tun mu ẹnikan wa lati ge waya ti o mu ina wa si inu ẹrọ amunatan naa ti wọn si wa sọ oun si inu okunkun patapata.

O wa n ke gbajare sita bayii pe, ẹmi oun ko de rara ti ewu n la si rọ mọ iru iwa bayii.

O wa ni ohun ti wọn ṣe yii lodi si ofin ti o si jẹ ohun itiju patapata si ipinlẹ Kogi ati orilẹede yii lapapọ ti o si le doju ti eto Ijọba awa arawa.

Ni bayii, o ti wa sọ pe oun yoo gba ile ẹjọ lọ lati beere fun idajọ ododo lori awọn iwa tani yoo mumi ti Gomina n hu.

Ni bayii, ẹni ti o jẹ igbakeji tuntun fun Gomina naa ni Edward Onoja ti wọn si ti bura wọle fun gẹgẹ bi ẹni ti yoo jẹ olukopa pẹlu gomina ninu idibo to n bọ.