Ẹ̀kún Omi: Ìgbáye-gbádún àrá Abeokuta já si òfò fáwọn ará Eko

Omokunrin ninu omi
Àkọlé àwòrán Bí ìgbáyegbádún àrá Abeokuta ṣe já si òfò ará Eko

Adagun omi Ọyan tí wọ́n ṣí ni ìlú Abeokuta, tií sọ ọ̀pọ̀ ènìyàn di aláìnílé lórí ní ìpiínlẹ̀ Eko, tí wọ̀n si ti di ẹdún àrinlẹ, ọ̀pọ̀ ní sọ́ọ̀bù àti ilé ìjọsìn wọ́n ti di èrò abẹ́ omi.

Ọ̀pọ̀ ẹ̀mi lo ti sọnu nítori ìṣẹ̀lẹ̀ náà, àwọn olùgbé Ajegunle àti Itolowo ní ijoba ibile Ikosi Isheri àti Agboyi-Ketu tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ẹ̀mí lo ti sòfò nítori ìsẹ̀lẹ̀ náà, tí omí si gbé àwọn míràn lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nítori ẹ̀kún omí náà, ìyá kan àti ọmọ rẹ̀ kan kú nígbà ti ọkọ̀ ojú omí tó n gbé wọ́n lọ dojúde, lẹ́yìn ọjọ́ kẹta si ni wọ́n to rí òkú ìyá àti ọmọ náà.

Ní àgbègbè Unity Estate Owode Onirin bákan náà, obinrin kan ti ẹnikẹni ko ti mọ orúkọ rẹ̀ ń gbìyànjú, lati wọ ọkọ oju omí lái mọ pé ejo ti wọ́ inu ọkọ náà, ti ejo naa si sàn-an, oró ejo yìí lo pa arabìnrin náà.

Ẹnikan lára olùgbé àdúgbò naa sàlàyé pé ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé àdúgbo ọhun ni wọ́n ti sá nile wọ́n, ti wọ́n si n bẹ ìjọba láti báwọ́n ṣe oju àgbàrá, ki ẹ̀kún omi le dínku.

Afolabi ni adagun odo ti wọn si ni Abeokuta lo sọ ọ̀pọ̀ dí ẹdun arinlẹ̀, bí àwọn ènìyàn ṣe ń ko kuro nile wọ́n, ní iṣẹ́ òòjọ tí di apati, ti ilé ìwé ko si ṣe lọ mọ fún àwọn ọmọ.

Àkọlé àwòrán Bí ìgbáyegbádún àrá Abeokuta ṣe já si òfò ará Eko

Adari Ogun-Osun Rivers Basin, Femi Dokunmu nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sàlàyé pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé lóòtọ́ ni àwọn ṣí adagun odo Oyan to ti ku jú bo se yẹ lọ nitori òjò àrọ̀ọ̀rọ̀ dá, síbẹ̀ ìgbésẹ̀ to yẹ ni àwọn ti gbé.

Dokunmu ní ojuse adagun odo ọhun ni láti dẹkun ẹkun omí àti ki àwọn odo ma kun akunfaya sùgbọ́n ojo ọdun yìí ti pọju lo fá awọn ijamba yii.

O ni àsìkò ẹẹrun ní àwọn máa n si omi náà tẹ́lẹ̀ ki òjò míràn to dé, èyí ti o si ti n ran wọ́n lọ́wọ́ ko to di àsìkò yìí.