Dangote: Ẹ̀ yin ọmọ Nàíjíríà, ẹ máṣe sọ ìrètí nù nípa ilẹ̀ wa

Aliko Dangote Image copyright @AlikoDANGOTE

Aliko Dangote, tii se ẹni to lowo julọ nilẹ Afirika ti kede pe ko ni su oun lati maa mu adinkun ba isẹ ati osi, ki oun si pin ọrọ oun kaakiri lati ipasẹ idokowo ti oun n se.

Dangote kede bẹẹ nigba to n fesi si osuba nla ti ẹni to jawe olubori ninu idije tileesẹ Dangote to n pese simẹnti se fawọn onibara rẹ nipinlẹ Ondo ati Delta.

Dangote, ẹni to rọ awọn ọmọ Naijiria lati mase sọ ireti ti wọn ni ninu orilẹede yii nu nitori pe ọla si maa dara, tun ni ohun ayọ lo maa n jẹ fun oun lati ran awọn alaini lọwọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa lo salaye pe oun mọọmọ maa dokowo kaakiri nitori ifẹ ti oun ni lati maa fi ọwọ kan awọn ti ko ri jajẹ lawujọ, ki oun si mu agbega ba igbe aye ọmọ Naijiria kọọkan.

O fikun pe ohun to mu ki idije ti ileesẹ simẹnti ohun se ni irufẹ ẹbun ti awọn onibara n jẹ, nitori afojusun ileesẹ naa ni lati ro onibara wọn lagbara latipasẹ idije ọhun.

Image copyright @AlikoDANGOTE

Ninu idije tileesẹ aposimẹnti Dangote se naa, ẹnikan to ti jẹ Kanselọ ri nijọba ibilẹ kan nilu Akurẹ, to ti wa di ẹni to n yọ bulọọku ile bayii lo jẹ ẹbun akọkọ.

Lara awọn ẹbun ti awọn onibara si jẹ ni ọkọ ayọkẹlẹ, kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta, ati ọkada, eyi ti yoo mu ki ọrọ aje awọn onibara Dangote ru gọgọ si, ti wọn yoo si tun ni anfaani lati dokowo ni ọna miran, ti owo yoo si tun maa wọle fun wọn.