Ondo Kidnap: Géńdé agbébọn jí adájọ́ gbé lọ ní ìpínlẹ̀ Ondo

Gende agbegbọn kan Image copyright @HQNigerianArmy

Iroyin kan to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti ni awọn eeyan kan ti wọn fura si bii ajinigbe ti ji adajọ ile ẹjọ giga ijọba apapọ kan gbe lọ nilu Akurẹ.

Adajọ naa, ti wọn pe orukọ rẹ ni Abdul Jogo la gbọ pe wọn ji gbe lọ pẹlu awakọ rẹ loju ọna Ibilo si Isua de Akoko, leti aala ilẹ ipinlẹ Ondo si Edo.

Iroyin naa ni adajọ Abdul Dogo lo n bọ lati ilu Abuja nigba ti awọn ajinigbe naa da lọna, ti wọn si ji gbe lọ.

Awọn agbẹjọro ati awọn osisẹ ileẹjọ to ti yẹ ki adajọ joko gbọ ẹjọ laarọ oni, lo fidi isẹlẹ naa mulẹ pe awọn ajinigbe ti ji adajọ lọ.

BBC Yoruba tiraka lati gbọ tẹnu osisẹ alarina fun ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Ondo, Femi Joseph, ko lee fidi isẹlẹ naa mulẹ, amọ ko tii gbe ipe wa lori aago.

Iroyin kan ti ko fidi mulẹ si ti n tan kaakiri pe awọn ajinigbe naa ti n beere aadọta miliọnu naira ki wọn to fi silẹ.

A ma mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOfada Rice: kíni ẹ̀yin gbádùn nínú ìrẹsì ọ̀fadà?