Ibadan Drivers Clash: Àjọ OYRTMA sọ ohun tó fa wàhálà láàrín àwọn awakọ̀

Tweet Image copyright Tajudeen Olajide
Àkọlé àwòrán Awọn awakọ Micra

Ajọ to n ri si igbokegbodo oju popo nipinlẹ Oyo, OYRTMA ti sọ pe, aitẹle ofin awọn awakọ lo ṣokunfa rogbodiyan to waye laarin ajọ naa ati awọn awakọ lagbegbe Sango, nilu Ibadan.

Adeoye Ayoade to jẹ adari ajọ ọhun lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ pelu BBC Yoruba.

O sọ pe ajọ OYRTMA ti gbiyanju lọpọ igba lati ri i pe, adinku de ba sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ lopopona Sango-Eleyele, Sango-Mokola ati Sango-Ojoo.

Adeoye ni rogbodiyan bẹ silẹ lẹyin ti awọn awakọ kan kọ ki ajọ ọhun fi ọwọ ofin mu wọn, lẹyin ti wọn ru ofin oju opopona leyi to n fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ lagbegbe ọhun.

Adeoye ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ OYRTMA ni ki awọn awakọ ọhun kuro ni ibi ti wọn wa tẹlẹ lọ si ibomiran, ki ọna lee ja gaara, ṣugbọn wọn kọ'ti ikun si aṣẹ ọhun.

O ni gbogbo akitiyan ajọ naa lati ko awọn awakọ "Micra" kuro ni ibudokọ ti wọn ti n ko ero ki ọna ọhun le ja gaara lo ja si pabo.

Image copyright @ibcityannouncer

O tẹsiwaju pe, ọpọ awọn oṣiṣẹ OYRTMA lo farapa nibi iṣẹlẹ ọhun.

Alukoro ajọ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Fadeyi Oluwagbenga fi idi ọrọ naa mulẹ.

O ṣalaye pe lootọ ni ajọ OYRTMA fi ofin mu ọkọ meji lati fi fa awọn awakọ yoku leti ki wahala to bẹ silẹ

Oluwagbenga ni ajọ ọlọpa da si awuyewuye ọhun, ṣugbọn ko si họhuhọhu kankan laarin awọn ọlọpaa ati OYTMA.

Gomina ipinlẹ ipinlẹ Ọyọ, amojuẹrọ Seyi Makinde si ti da si ọrọ naa lọna lati yanju rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÒwe: Kí ni ìtumọ̀ òwe ikú tó ń pa ojúgbà ẹni?