Sex for Grades: Fasiti Kaduna ni ki olùkọ́ lọ rọọ́kún nílé

fasiti kaduna

Oríṣun àwòrán, @kadunauniv

Àkọlé àwòrán,

Sex for Grades: Fasiti Kaduna ni ki olùkọ́ lọ rọọ́kún nílé

Kete ti iroyin yii jade ni awọn alaṣẹ ile ẹkọ giga fasiti Kaduna ti kede pe ki olukọ ti wọn fi ẹsun naa kan lọ rọọkun nile.

Omowe Tukur Abdulkadir to jẹ igbakeji aarẹ ẹka to n ṣamojuto ọrọ awọn akẹkọọ ni fasiti Kaduna lo ṣiṣọ loju ọrọ naa.

O ni bi ọmọbinrin yii (ti wọn fi orukọ bo laṣiri) ṣe ti rirnirn ijajangbara abo kuro lọwọ awọn olukọ to n halẹ mọ awọn akẹkọọ ni iwadii ti bẹrẹ.

Omobinrin yii fẹsun kan olukọ yii pe o filọkulọ lọ ohun ni eyi ti awọn alaṣẹ fasiti Kaduna dẹ ti ni ko lọ rọọkun nile titi iwadii a fi pari.

Nibi ipade igbimọ alabẹṣekele ti KASU ṣe ni wọn ti ni ki Ogbeni Bala Umar ti ọpọ awọn akẹkọọ n pe ni AB Umar lọ rọọ kun nile.

Omobinrin yii fẹsun kan Umar pe wọn le Umar ni fasiti Ahmadu Bellu (ABU) ni Zaria nitori pe o n fi ilọkulọ lọ awọn akẹkọọbinrin ni eyi to wa ya oun lẹnu pe fasiti Kaduna gbaa siẹẹ.

Ojọgbọn Abdulahi Ashafa to jẹ igbakeji ọga agba ile iwe KASU lo ṣe alaga igbimọ to pe ipadepajawiri naa ni Kaduna.

Àkọlé fídíò,

Ogun flood: ọ̀ps àwọn olùgbé agbegbe yii ti fi iṣẹ́ sílẹ̀ nítorí wọn kò lè jáde

Abdulahi ni KASU ko ni faaye gba ki olukọ maa dunkooko mọ akẹkọọ rara.

Lẹyin ti fidio BBC jade lori awọn olukọ fasiti Eko ti wọn n huwa buruku yii ni ọmọbinrin naa fi soju opo twitter pe Umar ti huwa buruku yii si oun ri ni fasiti ABU.

Ashafa ni bo tilẹ jẹ pe iṣẹlẹ yii ko ṣẹlẹ ni KASU, o di dandan ki KASU gbe igbesẹ to yẹ ki ọkan awọn obi ati alagbatọ awọn akẹkọọ le balẹ.