Russia-Africa summit: Wo àdéhùn méje tí Buhari ṣe pẹ̀lú ilẹ̀ Russia

Russia-Africa summit: Image copyright NIGERIA PRESIDENCY
Àkọlé àwòrán Orílẹ̀-èdè mẹ́rindínláàdọ́ta ni wọ́n wà ní ibi ìpàdé ìjíròrò láàrin orílẹ̀éde Afirika àti orílẹ̀èdè Russia.

Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari wa lara orilẹ-ede mẹrindinlaadọta ti wọn wa ni ibi ipade ijiroro laarin orilẹ-ede to wa ni Afirika ati Russia.

Buhari lasiko to n ba Aare orilẹ-ede Russia, Vladmir Putin sọrọ, pinnu lati rii wi pe ibasepọ to dan mọran wa laarin orilẹ-ede mejeeji.

Image copyright NIGERIA PRESIDENCY

Aarẹ mejeeji pinnu lati ri wi pe wọn pari awọn akanṣe ti wọn ti bẹrẹ lorilẹ-ede Naijiria paapaa eleyii to niiṣe pẹlu ẹka epo rọọbi ni Naijiria.

Ọrọ karakata ati idokowo, eto aabo ati iranwọ fun ẹka ọmọogun orilẹ-ede Naijiria.

Wo adehun meje ti Buhari se pelu ilẹ Russia

  • Naijiria ati Russia ti ṣe adehun lati ri i wi pe ibaṣepọ to dan mọran wa laarin Ajọ NNPC ti Naijiria ati Ajọ Afẹfẹ Gaasi, Gazprom ti ilẹ Russia.
  • Orilẹ-ede Russia tun ṣe adehun lati ri wi pe Ajaokuta Steel Rolling Mill ti wọn ti kọ silẹ lati ọdun gbooro tun dide pada.
  • Bakan naa ni orilẹ-ede mejeeji ṣe adehun lati ṣe papakọ ohun ijagun ọlọgọọrọ,eleyii ti wọn yoo bẹrẹ laipẹ.
  • Orilẹ-ede Russia naa tun gba lati mu ajinde ba adehun to niiṣe pẹlu iranwọ fun ikọ ọmọogun orilẹ-ede Naijiria.
  • Ibaṣepọ yoo tun wa lori ọrọ eto ẹkọ ati eto ọgbin.
  • Bakan naa ni awọn adari mejeeji jiroro lori ẹka to n risi eto abo ninu Ajọ Isọkan Agbaye, eleyii ti Naijiria n fẹ lati wa lara ajọ naa titi lai.

Jumọkẹ Odetola ṣe ọjọ́ ìbí, Wumi Toriola bímọ, Ṣé ẹ fẹ́ tẹ̀lẹ́ Funkẹ Akindele lọ si Dubai?

Kò sí àrùn 'Monkey Pox' ní Naìjiria- NCDC

Ìdí tí a ṣe yọ ọwọ́ Naira Marley kúrò láwo Headies Award ọdún yìí rèé - HipTV

'O ṣójú mí kóró bí wọ́n ṣé fí àdó olóró pa Dele Giwa lọdún 1986'

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÒwe: Kí ni ìtumọ̀ òwe ikú tó ń pa ojúgbà ẹni?