Kunle Afod: Ohun mẹ́wàá tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa Kunle Afod ti Yollywood

KUNLE AFOD

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM

Àkọlé àwòrán,

Gbajúgbajà Òsèré Yoruba, Kunle Afod ti kópa nínú fíímù bíi Nkan agba, Odi ade, Ofin kokanla, Pitan ati Orindola.

Ọjọ Kẹrinlelogun, Osu Kẹwaa, ọdun 1973 ni wọn bi gbajugbaja osere Nollywood, Kunle Afod ni ilu Eko, amọ ipinlẹ Oyo ni wọn ti bi awọn obi rẹ.

Ọkunrin ilumọọka naa jẹ ẹni to mọ tinu tẹyin sisẹ ere agbelewo ni ẹka amuludun lorilẹ-ede Naijiria.

Arakunrin Afod jẹ ọkan lara awọn oṣere ti ajé ba ṣọrẹ. o n dari ere, o tun n ya aworan pẹlu.

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM

Ohun mii to yẹ ko mọ nipa Kunle Afod

  • Arẹwa osere naa ni akọbi ninu ọmọ mẹrin ti iya ati baba rẹ bi.
  • Ile Iwe alakọbẹrẹ ni Festac ni ilu Eko ni Afod ti lọ si ile iwe, ti o si lọ pari rẹ ni ilu Ọwo ni ipinlẹ Ondo.
  • Ile iwe ọmọogun Command ni ilu Jos ni o ti pari ile iwe girama.
  • Kunle gbe aya rẹ, Desola ni iyawo.
  • Ọmọ ọkunrin mẹrin naa ni Kunle Afod ti bi ninu igbeyawo rẹ pẹlu iyawo rẹ Desola Afod.
  • Gbajugbaja Osere Yoruba, Kunle Afod ti kopa ninu fiimu Nkan agba, Odi ade, Ofin kokanla, Pitan, Orindola, Ade ferrari, Wura ati Fadaka, Awolu ati Awawu ati bẹẹ bẹẹ lọ.
  • Desola Afod bi awọn ọmọ mẹrin yii pẹlu iṣẹ abẹ ni eyi to fi maa n gba awọn obinrin nimọran.
  • Kunle ti pe ọmọ ọdun mẹrinlelogoji bayii.
Àkọlé fídíò,

Ogun flood: ọ̀ps àwọn olùgbé agbegbe yii ti fi iṣẹ́ sílẹ̀ nítorí wọn kò lè jáde