"Ministry of Communication" gba orúkọ tuntun

Iléeṣẹ́ tí ààrẹ yí padà sí Ministry of Communication and Digital Economy

Oríṣun àwòrán, OTHER

Ni ireti ati mu igbega ba eto ibanisọrọ ni Naijiria, Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe afikun si ile iṣẹ eto ibanisọrọ ilẹ yii.

Bayii, lati ile iṣẹ eto ibanisọrọ, o ti wa di ile iṣẹ eto ibanisọrọ ati ọrọ aje igbalode [Ministry Of Communication and Digital Economy].

Lori ọrọ yii, pupọ lara ọmọ Naijiria ni wọn ti n fesi si iyipada ti Ijọba apapọ muba ile iṣẹ naa ti ọpọ si n fi ehonu han bakan naa.

Ọpọ dahun wipe, yiyi orukọ pada kọ ni koko ṣugbọn ki Ijọba ṣe ohun to yẹ lasiko ki wọn si jẹ ki ile iṣẹ naa o ja fafa

Bakan naa ni ẹnikan tun fesi wi pe, orukọ naa ko buru ṣugbọn, kini anfaani ti yoo ṣe nigba ti ọpọ eniyan ba wa lori iduro lati gbowo ni banki.

Ẹlomiran wi pe, kii ṣe ayipada orukọ la fẹ ṣugbọn, ki a mu ayipada ba ihuwaa wa ati iṣesi wa lati mu igba ọtun wọle wa ba wa ni Naijiria.

Ninu ifesi ọkan lara awọn ti o n fọkan ba eto naa lọ, o ṣalaye pe awọn ọdọ naa le jẹ anfani naa nipa jijẹ ẹni ti o mọ nipa ẹrọ ayelujara dipo bibẹnu atelu Ijọba.

Ẹni ọrọ naa ka lara kan, ṣalaye pe, eto to daa ni ti o si rẹwa ṣugbọn ki ijọba gbiyanju lati mu eto ikọni ba awọn ti yoo ṣiṣẹ ni ile iṣẹ naa.

Oríṣun àwòrán, @Bashir Ahmad

Àkọlé àwòrán,

Eya kan lara leta naa ti o fi ayipada naa han